Gomina Sanwo-Olu kede iye ti yoo maa fun owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju

 Monisọla Saka

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti ni ẹgbẹrun marundinlaaadọrun-un (85,000) Naira, lowo oṣu oṣiṣẹ to kere ju, toun yoo maa san nipinlẹ Eko.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni gomina kede eyi nibi ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin kan.

Lasiko to n sọrọ lori awọn eto tijọba ni lọkan nipinlẹ naa ati akitiyan wọn lati koju awọn iṣoro laarin ilu, lo kede owo oṣiṣẹ to kere ju, to ju aadọrin ẹgbẹrun tijọba apapọ paapaa lawọn yoo maa san lọ.

O ni idi ti iye tawọn fẹẹ maa san l’Ekoo fi ju tijọba apapọ lọ ni bi agbara awọn ṣe gbe e si, ati bi nnkan ṣe gbowo lori yatọ nipinlẹ Eko.

O ni pẹlu idunnu loun yoo tun fi kede owo-oṣu to kere ju mi-in, ninu oṣu Kin-in-ni, ọdun to n bọ.

O ni, “Ẹ tun sọrọ nipa owo-oṣu to kere ju ati nnkan ti mo ni lati ṣe fawọn eeyan mi. Inu mi dun lati kede pe owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju nipinlẹ Eko, ta a ti ba awọn eeyan wa sọ di ẹgbẹrun marundinlaaadọrun-un Naira lonii, ki i si ṣe ọrọ ifigagbaga, nitori bẹẹ ni mi o ṣe ni i sọ pe a n sanwo ju awọn eeyan kan lọ. Ọrọ nnkan ti agbara wa ka ni, ati lori ọrọ bi nnkan ṣe wọn”.

“A fowo kun owo oṣu oṣiṣẹ nibẹrẹ ọdun yii, yoo si wu wa lati tun pada wa ninu oṣu Kin-in-ni, ọdun to n bọ, pe mo tun ti fi kun owo oṣiṣẹ to kere ju l’Ekoo, si ọgọrun-un ẹgbẹrun (100,000)”.

Tẹ o ba gbagbe, ninu oṣu Keje, ọdun yii, nijọba apapọ kede ẹgbẹrun lọna aadọrin Naira gẹgẹ bii owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju lorilẹ-ede yii, lẹyin ọpọlọpọ fa-n-fa-a laarin awọn ati ẹgbẹ oṣiṣẹ mejeeji nilẹ Naijiria, iyẹn Nigeria Labour Congress (NLC) ati Trade Union Congress (TUC).

Leave a Reply