Adewale Adeoye
Pẹlu ọrọ ti Minisita fun olu ilu ilẹ wa, Abuja, Ọgbẹni Nysome Wike, sọ laipẹ yii, laarin ọjọ marun-un sigba ta a wa yii, awọn oṣiṣẹ amunifọba iyẹn Taskforce l’Abuja maa too maa lọọ kaakiri igberiko ilu naa lati maa fọwọ ofin mu gbogbo awọn onibaara ti wọn n rin gberegbere kaakiri aarin ilu naa.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni Wike sọrọ naa di mimọ lasiko to lọọ ṣe ifilọlẹ ṣiṣe ojuna marosẹ kan l’Abuja.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘‘A ko ni i laju wa silẹ ki talubọ ko wọ ọ. Laarin ọjọ marun-un sigba ta a wa yii, a maa too bẹrẹ si i ko awọn onibaara gbogbo kuro nilẹ laarin ilu Abuja.
Bo ba maa fi di ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ to n bọ yii, o ti deewọ fawọn onibaara ki wọn maa tọrọ owo kaakiri ilu naa bayii. A ko ni i gba pe ki wọn maa rin kaakiri ilu mọ. Itiju nla leyi n ko ba orileede Naijiria lagbaaye. Ọpọ ninu awọn onibaara wọnyi lo jẹ pe iṣẹ agbodegba awọn jaguda ni wọn n ṣe. Wọn n ran awọn oniṣẹ ibi lọwọ. A gbọdo fopin si i. A n fi akoko yii sọ fawọn araalu yooku pe ki wọn waa ko awọn eeyan wọn gbogbo ti won n ṣiṣẹ baara niluu Abuja. Ba a ba waa ri onibaara kan to kọ eti ikun si ofin naa, aa jiyan rẹ niṣu ni, ko saaye fun iranu lasiko iṣakooso ijọba yii, a ko ni i fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ awọn onibaara naa mọ, ijọba orileede yii n gbiyanju gidi lati pese awọn ohun amayedẹrun fun araalu, ṣugbọn bawọn onibaara yii ṣe n lọ kaakiri igberiko ki i ṣohun to daa, a gbọdọ fopin si i. Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ to n bọ la fun wọn da’.