Wọn ti gbe Bobrisky digbadigba lọ sileewosan o, wọn lara rẹ ko ya gidigidi

Adewale Adeoye

Ki i ṣe iroyin mọ pe wọn ti fọwọ ofin mu gbajumọ ọmọ jayejaye nni, Idris Okunnẹyẹ, tawọn eeyan mọ si Bobrisky, lasiko to fẹẹ dọgbọn sa filu silẹ lọ sorileede Benin. Ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, ni wọn gba a mu, latigba naa lo si ti wa lahaamọ ileeṣẹ ọlọpaa ri wọn ti n wadii ẹsun ọdaran, ‘‘Force Criminal Investigation Department’’ (FCID), Alagbọn, nipinlẹ Eko.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago meji ọsan Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, nileeṣẹ ọlọpaa ni Alagbọn, sare gbe e digbadigba lọ sileewosan ijọba kan to wa lagbegbe Falọmọ, nipinlẹ Eko, nigba to n pariwo buruku pe igbaaya n dun oun lahaamọ to wa.

Ere lawọn ọlọpaa kọkọ n pe e nigba to n yira mọlẹ nibi to wa, nigba ti alabọrun fẹẹ dẹwu mọ ọn lọrun ni wọn too gbagbọ pe loootọ ni nnkan n ṣe e. Kia ni wọn ti gbe Anbulaansi, iyẹn mọto ti wọn fi maa n gbe alaisan jadem ri wọn si fi gbe e lọ sileewosan ijọba to wa ni Falọmọ, nipinlẹ Eko, fun itọju to peye.

Ki awọn araalu ma baa mọ pe oun lo wa ninu ọkọ naa, ṣe ni wọn fi aṣọ kekere kan bo o lori lasiko ti wọn n gbe e sinu anbulaansi naa.

A gbọ pe eto ti n lọ lọwọ tẹlẹ lati gbe e lọ si ẹka ileesẹ ọlọpaa to n mojuto sun jibiti, ‘Special Fraud Unit’ (SFU) nibi ti kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Eko gan-an wa, ki wọn baa le mojuto o, ṣugbọn nigba ti ajalu mi-in de lojiji ni wọn ṣe kuku sọ pe ki wọn kọkọ gbe e lọ sileewosan na.

Ọjọ Aje, Mọnnde, ọsẹ yii ni ALAROYE gbe iroyin ọhun jade pe awọn agbofinro orileede yii fọwọ ofin mu un lẹnuubode lasiko to fẹẹ wọ orileede Benin.

Ọjọ Aje, Mọnnde, lo yẹ ko lọọ yọju sawọn ọmọ ileegbimọ aṣofin agba l’Abuja, ṣugbọn to fẹẹ dọgbọn sa filu silẹ, ko too di pe ọwọ tẹ ẹ.

Leave a Reply