Ẹgbẹ APC ni ki Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla lọọ rọọkun nile, eyi lohun ti wọn lo ṣẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ẹgbẹ osẹlu All Progressives Congress (APC), nipinlẹ Ọṣun, ti sọ pe ki minisita fun ọrọ abẹle lorileede yii nigba kan, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, lọọ rọọkun nile.

Igbesẹ naa ko ṣẹyin ẹsun oniruuru ti wọn fi kan Arẹgbẹṣọla, ẹni to ti figba kan jẹ gomina nipinlẹ Ọṣun, ninu eyi ti wọn ti ni o pin ẹgbẹ naa si meji.

Ẹsun mẹfa ọtọọtọ ni awọn ọmọ ẹgbẹ APC nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ileṣa, ti Arẹgbẹṣọla ti wa fi kan an gẹgẹ bo ṣe wa ninuu lẹta ti wọn fi ṣọwọ si awọn alaṣẹ ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọṣun.

Awọn ẹsun naa ni pe o da ẹgbẹ tuntun silẹ ninu ẹgbẹ APC, o pin ẹgbẹ si meji nipa dida igun to pe ni Omoluabi Caucus silẹ, ifidimulẹ eleyii ti wọn lo wa ninu fọnran fidio ipade kan ti wọn ṣe niluu Iwo, laipẹ yii, wọn ni o n ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ẹgbẹ alatako lati yẹpẹrẹ ẹgbẹ APC l’Ọṣun gẹgẹ bo ṣe fidi mulẹ laafin Ataọja lọjọ kẹrin, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024.

Bakan naa ni wọn ni o maa n sọrọ aleebu si awọn adari ẹgbẹ naa bii Aarẹ orileede yii, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, Oloye Bisi Akande, Alhaji Gboyega Oyetọla ati bẹẹ bẹẹ lọ, pẹlu bi ko ṣe dibo tabi kopa ninu akitiyan ẹgbẹ naa latigba idibo apapọ ti ọdun 2019.

Awọn ẹsun naa, gẹgẹ bi Akọwe igbimọ to n ṣebawi awọn ọmọ ẹgbẹ naa, Waheed Adediran, ṣe sọ, ni wọn ni o ta ko abala ikọkanlelogun iwe ofin ẹgbẹ yii.

Wọn waa fun Arẹgbẹṣọla lanfaani lati dahun si awọn ẹsun ti wọn fi kan an laarin wakati mejidinlaaadọta ti lẹta naa ba tẹ ẹ lọwọ.

Igbimọ naa sọ siwaju pe esi ti Arẹgbẹṣọla ba fun awọn lori awọn ẹsun naa ni yoo jẹ ọpakutẹlẹ fun abajade iwadii awọn, nitori awọn ko fẹẹ role apa kan da apa kan si lawọn ṣe fun un lanfaani lati waa wi tẹnu rẹ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an wọnyi.

Leave a Reply