Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ti yan Ọlamilekan Moshood Agbelesebiọba tawọn eeyan mọ si Laycon ninu ere ‘Big Brother Naija’ to ṣẹṣẹ pari gẹgẹ bii aṣoju awọn ọdọ nipinlẹ Ogun, bẹẹ lo tun fun un ni miliọnu marun-un ati ile adagbe oniyara mẹta tuntun.
Ọjọ Iṣẹgun,Tusidee, ọjọ kẹfa, oṣu kẹwaa, ọdun 2020, ni gbogbo eyi waye, nigba ti Laycon ṣabẹwo si Gomina Dapọ Abiọdun lọfiisi rẹ l’Oke-Mosan, l’Abẹokuta.
Gomina ṣapejuwe iwa Laycon ninu ile BB Naija naa gẹgẹ bii ti ọmọluabi, o ni jijẹ ọmọluabi si ni nnkan akọkọ tawọn ọmọ ipinlẹ Ogun ti Lekan ti wa maa n ni.
O fi kun un pe pẹlu gbogbo afojuri ti ọmọ yii ri nile naa, o yege nibẹ lai jẹ pe ẹnikẹni ri aleebu kankan latọdọ ẹ titi ti wọn fi pari ere yii.
Gomina tun ṣalaye pe Lekan fi han pe Yunifasiti Eko lo ti kawe gboye, bẹẹ lo ni oun nigbagbọ pe aṣeyọri ọmọ yii yoo jẹ awokọṣe fawọn ọmọ ipinlẹ Ogun mi-in lati ṣe daadaa. Wọn yoo le ronu ọna ati la yatọ si ‘Yahoo’, ole jija, ṣiṣe ẹgbẹ okunkun, ijinigbe atawọn iwakiwa to kun awujọ wa.
Bakan naa ni Abiọdun sọ pe awọn obi ati alagbato gbọdọ mọ pe ki i ṣe ileewe nikan lọmọ ti n ṣoriire, o ni awọn adanilaraya bii eyi naa n kopa ninu idagbasoke orilẹ-ede.
Ijọba ibilẹ Ọdẹda, ni Arin-Gbungbun Abẹokuta ni wọn ti bi Ọlamilekan Agbeleṣebiọba. Inu ọmọ naa dun pupọ si ohun ti gomina ṣe fun un yii, o dupẹ lọwọ Dapọ Abiọdun fun bo ṣe n ko awọn ọdọ mọra ninu iṣejọba ẹ, o si ṣeleri pe oun yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba lati gbe ipinlẹ Ogun ga.
Ṣugbọn ero awọn eeyan ko ṣọkan lori ohun ti Gomina Abiọdun ṣe fun Lekan yii, niṣe lawọn kan n sọ pe ko yẹ ki gomina fun un lowo to to bẹẹ.
Wọn ni eeyan ṣabẹwo ọjọ kan ṣoṣo si i, gomina fun un ni miliọnu marun-un ati ile oniyara mẹta. Wọn ni owo oṣiṣẹ-fẹyinti mi-in to fi ọdun marundinlogoji sin ijọba ko to miliọnu marun-un ti ọmọ yii gba lọjọ kan ṣoṣo yii, bẹẹ o ti di olowo tẹlẹ ko too tun maa waa gba ninu owo ipinlẹ Ogun yii.
Bẹẹ lawọn mi-in si n sọ pe ko sohun to buru ninu ohun ti gomina ṣe. Wọn ni Lekan paapaa yoo sanwo ori ninu owo rẹ to gba ni BB Naija, ipinlẹ Ogun ni yoo si san an fun. Ati pe nigba to jẹ ọmọ ipinlẹ Ogun lọmọ naa, oore ti gomina ṣe fun un ko gbe, oko ẹmọ naa lẹmọ lọ ni.