Adewale Adeoye
Ọmọ ọlọjọọbi kan ti ṣe pati daran bayii, ọjọ ti iba si jẹ ọjọ ayọ fun un naa pada ja si odi keji pẹlu bi awọn amunifọba nipinlẹ Eko, ‘The Lagos State Taskforce’ ṣe nawọ gan-an lasiko ti ayẹyẹ ọjọọbi rẹ n lọ lọwọ. Eyi ko sẹyin ofin ipinlẹ Eko kan ti wọn lo tapa si.
Awọn agba bọ wọn ni, ‘ilu ti ko ba sofin, ẹṣẹ ko si nibẹ’, ṣugbọn lọjọ ti ofin ba ti bẹrẹ, ẹṣẹ ti bẹrẹ niyẹn. Eyi lo mu ki Ọrọ yii lo ṣẹ rẹgi plu ofin tijọba ipinlẹ Eko gbe kalẹ bayii pe o ti deewọ faraalu Eko lati ṣe pati loju titi nipinlẹ naa bayii. Wọn ni beeyan kan ba dan aṣa palapala bẹẹ wo lasiko yii, aa jiyan rẹ niṣu ni.
Ajọ amunifọba kan nipinlẹ Eko, ‘The Lagos State Taskforce’ lo ṣekilọ pataki ọhun niluu laipẹ yii pe ko sigba ti awọn eeyan maa di oju titi pa nitori ayẹyẹ inawo wọn ti ki i mu inira nla ba awọn araalu yooku, ti ko si yẹ ko ri bẹẹ rara.
Wọn ni gbogbo ọna to ba ofin mu lawọn maa gba bayii lati ṣamulo ofin to ti wa nilẹ tẹlẹ lati foju awọn afurasi ọdaran gbogbo ti wọn ba tapa sofin ipinlẹ Eko bale-ẹjọ.
ALAROYE gbọ pe aipẹ yii lawọn ajọ amunifọba ọhun lọọ fọwọ ofin mu awọn araalu marun-un kan lagbegbe Raymond Njokwu, nipinlẹ Eko, lasiko ti wọn n ṣayẹyẹ ọjọọbi lọwọ, ti wọn si di gbogbo oju titi pa patapata, tawọn araalu ko si rọna gba kọja mọ.
Kọmiṣana ọrọ ayika nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Tokunbo Wahab, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹwaa, ọdun yii sọ pe, lara awọn afurasi ọdaran tawọn fọwọ ofin mu lagbegbe Raymond Njokwu ọhun ni ọmọ ọlọjọọbi gan-an, olorin taka-sufee ti wọn pe, atawọn mẹta mi-in.
O ni laipẹ yii lawọn maa foju awọn afurasi ọdaran naa bale-ẹjọ fohun ti wọn ṣe, ki wọn le jiya ẹṣẹ to tọ si wọn labẹ ofin.