Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ko din ni gende marunlelaaadọta (55), tọwọ ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, Economic Financial and Crimes Commission (EFCC), ba lawọn igboro ilu Ọffa, nipinlẹ Kwara, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 yii. Wọn ni jibiti ori ẹrọ ayelujara ti wọn n pe ni ‘Yahoo Yahoo’ lawọn ọdọ naa n ṣe.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro EFCC, Ọgbẹni Dele Oyewọle, fi lede niluu Ilọrin, to tẹ ALAROYE lọwọ, lo ti ṣalaye pe ọpọ lara awọn afurasi ọdaran ti wọn mu naa ni wọn jẹ akẹkọọ lawọn ile ẹkọ giga, ṣugbọn kaka ki wọn dojukọ ẹkọ wọn, iwa gbaju-ẹ ni wọn n hu lori intanẹẹti, o ni awọn inu ile ti awọn afurasi naa fara pamọ si lọwọ ti tẹ wọn.
Lasiko tọwọ ba wọn, ọkọ ayọkẹlẹ bọginni mẹsan-an, ọpọlọpọ foonu igbalode, kọmputa agbeletan, atawọn nnkan mi-in to lodi sofin ni wọn ba nikaawọ wọn.
EFCC, ẹka tilu Ilọrin. to ṣiṣẹ naa ti taari awọn afurasi ọdaran yii sọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ fun iwadii to lọọrin, ki wọn le foju wọn bale-ẹjọ laipẹ
Tẹ o ba gbagbe, laarin ọjọ kẹta si ọjọ kẹfa, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024 yii, lọwọ ajọ ọhun tẹ awọn afurasi alujibi lori ayelujara to n lọ bii ọgọrun-un kan niye nigbooro ilu Ilọrin, ti i ṣe olu fun ipinlẹ Kwara, ti wọn si ti n kawọ pọnyin rojọ niwaju awọn adajọ.