Idaamu Bobrisky, EFCC ti tun mu un ju sahaamọ

Jọkẹ Amọri

O jọ pe ọrọ awọn wolii ti wọn riran si ọmọkunrin to maa n mura bii obinrin nni, Idris Okunnẹyẹ, ti gbogbo eeyan mọ si Bobrisky, pe yoo la ọpọlọpọ iṣoro kọja lọdun yii ti n ṣẹ.

Ọrọ ọmọkunrin ti wọn maa n pe ni Mummy of Lagos yii ti waa di egbinrin ọtẹ bayii, bi wọn ṣe n pa ọkan ni omi-in n ru, ko si jọ pe yoo bọ ninu eyi to tun ṣẹlẹ si i yii bọrọ, nitori awọn amunimadaa to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku nilẹ wa lo tun mu un ṣinkun nigba to fẹẹ tẹ baaluu leti lati maa lọ si orileede UK, lati lọọ fara nisinmi lori gbogbo lọgbọlọgbọ tawọn aṣọbode atawọn ọlọpaa ba a fa ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin.

ALAROYE gbọ pe ilu London, ni Bobrisky n lọ, o ti ko ẹru rẹ sinu ọkọ ofurufu, o si ti wa ninu baaluu, afi lojiji ni gbogbo nnkan daru, ti ọrọ naa si di girigiri, n lawọn oṣịṣẹ to n mojuto iwọle ati ijade awọn eeyan lorileede wa ti wọn n pe ni Imigreṣan ba lọọ rẹbuu ẹ ninu ọkọ ofurufu, wọn fẹẹ wọ ọ bọ silẹ.

Ṣe oju bọrọ kọ la fi n gba ọmọ lọwọ ekurọ ni Bobrisy fọrọ naa ṣẹ, niṣẹ loun naa ko agidi bori ti ko fẹẹ bọ silẹ, n loun atawọn alaṣẹ ijọba naa ba n wọdimu. Asiko naa ni wọn sẹ Mummy of Lagos leṣe lọwọ, ti ọwọ rẹ si daranjẹ. Ṣugbọn pẹlu ẹ naa, wọn wọ ọ bọ sita, wọn si n ti i lọpọnpọ-ọn lọ sinu papakọ ofurufu pada.

Bobrisky naa ko gbẹnu dakẹ o, o rapala ṣe fidio kan to gbe sori ayelujara, nibi to kọ ọ si pe, ’’Ẹyin ọmọ Naijiria ẹ gba mi o, wọn ti tun n mu mi lọ o, ẹ wo bi wọn ṣe ṣe mi’’ lo ba gbe awọran ibi ti wọn ti ṣe e leṣe si i.

ALAROYE gbọ pe ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku ni wọn tun mu ọmọkunrin yii, ko si ti i sẹni to mọ ohun ti wọn tun tori ẹ mu un lẹẹkeji, tabi ibi ti wọn mu un lọ.

Pẹlu bi nnkan ṣe ri yii, afaimọ ki wọn ma tun foju ẹ bale-ẹjọ lẹẹkeji, bi ko ba si ni agbẹjọro to mu lẹnu bii abẹ, ọgba ẹwọn Kirikiri lo tun n kọwe si niyẹn.

Bẹ o ba gbagbe, ọsẹ bii meji sẹyin ni awọn aṣọbode ilẹ wa mu un ni bọda Sẹmẹ, lasiko to fẹẹ kọja si orileede Bẹnnẹ. Ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si iwa ọdaran to wa ni Alagbọn, nipinlẹ Eko, ni wọn mu un lọ. Ibẹ lo si wa fun ọjọ diẹ ko too di pe wọn da a silẹ pe ko maa lọ. Bẹẹ ni igbimọ ti wọn gbe kalẹ lati wadii awọn ẹsun ti wọn fi kan an ni ko jẹbi, wọn ni ko sẹni to fun ni owo abẹtẹle kankan, bẹẹ lo sun si ọgba ẹwọn ni gbogbo oṣu mẹfa to fi yẹ ko wa nibẹ.

Bi Bobrisky ti jade ni Alagbọn lo ti gba ori ayelujara lọ, to mura dẹndẹn bii orekelẹwa obinrin, to si n gba awọn eeyan niyanju pe ki wọn ma ri ohun ti wọn n la kọja gẹgẹ bii ipenija ti yoo gbe wọn ṣubu, ṣugbọn ki wọn ṣe ọkan akin, ki wọn ma si ṣe jẹ ki awọn eeyan maa kaaanu wọn.

Latigba ti Bobrisky ti ti ọgba ẹwọn to lọ de lo ti n ko lati inu wahala kan si ekeji, ko si sẹni to ti i le sọ bi eyi to ko ara rẹ si bayii yoo ṣe ri. Ṣe awọn wolii kan kuku ti rinna si i nibẹrẹ ọdun yii pe yoo maa ko lati inu iṣoro kan si omi-in ni.

Ohun ti awọn ololufẹ rẹ n sọ ni pe kin ni ọmọkunrin naa ṣe fun wọn, ṣe wọn fẹẹ pa a ni, ki ijọba fi ọmọkunrin naa silẹ. Bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe ẹni to ba ṣe ohun ti ẹnikan ko ṣe ri ni ọrọ Mummy of Lagos, oju rẹ gbọdọ ri ohun ti ẹnikan ko ri ri.

Leave a Reply