Adeleke, inira yii pọ o, sanwo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ ijọba – TOM

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

The Osun Masterminds (TOM), ti ke si Gomina Ademọla Adeleke lati bẹrẹ si i san owo-oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ ijọba, ki ara le tu gbogbo araalu.

Nibi ipade oniroyin oloṣooṣu ti ẹgbẹ naa ṣe niluu Oṣogbo, ni Alakooso rẹ, Ọjọgbọn Wasiu Oyedokun-Alli, ti sọ pe ijọba apapọ ati awọn ijọba ipinlẹ ko ṣeto lati din idaamu ti awọn araalu n koju lasiko yii ku.

O ni tijọba apapọ ba kan tiẹ kọ iha ko-kan-mi si wahala awọn araalu n la kọja, ewo ni ti awọn ijọba ipinlẹ ti wọn n gba owo nla nla latọdọ ijọba apapọ bayii.

TOM ṣalaye pe iyalẹnu lo jẹ fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ipinlẹ Ọṣun pe ijọba Gomina Adeleke ko sọ nnkan kan lori owo-oṣu awọn oṣiṣẹ to kere ju, iyẹn ẹgbẹrun lọna aadọrin Naira, tijọba apapọ kede laipẹ yii.

O ni pupọ awọn ipinlẹ ni wọn ti kede iye ti wọn lagbara lati san, ṣugbọn dipo ki Adeleke kede tiẹ, biriiji lo n ṣe kaakiri awọn agbegbe ti ko nilo biriiji, ti ebi si n pa awọn araalu.

Ẹgbẹ naa ran ijọba leti pe ti aye ba ti gbẹdẹmukẹ fun awọn oṣiṣẹ ijọba, o di dandan ko ran awọn araalu, bẹrẹ latọdọ awọn iyalọja ati oniṣowo kekeke.

TOM waa gboṣuba fun ijọba Adeleke lori igbesẹ bo ṣe fofin de awọn ọkọ nla nla lati ma ṣe gun ori biriiji abẹyẹfo orita Ọlaiya, niluu Oṣogbo, mọ, ṣugbọn o bu ẹnu atẹ lu bijọba ṣe gbe ọrọ naa kalẹ, eleyii to yọri si ede aiyede laarin ijọba atawọn ẹgbẹ oṣelu alatako.

Bakan naa ni wọn ke si awọn ti wọn wa nijọba lati mọ pe oju lo pẹ si, eegun yoo pada di eeyan, ki wọn din ina apa ku, ki wọn si lo owo to n wọle sasunwọn ijọba fun idagbasoke agbegbe.

Leave a Reply