Adewale adeoye
Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ti bura fawọn minisita meje tuntun to ṣẹṣẹ yan lẹyin tawọn ọmọ ileegbimọ aṣofin agba l’Abuja ti fontẹ lu wọn pe wọn yege.
Lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹrin, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni eto pataki ọhun waye ninu ọkan lara awọn gbọngan igbalejo to wa ninu Aso Rock, l’Abuja.
Bẹ o ba gbagbe, ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin bayii, lẹyin ti Aarẹ Tinubu de lati Oke-Okun to ti lọọ sinmi lo forukọ awọn minisita naa ṣọwọ si awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin agba l’Abuja, pe ki wọn yẹ wọn wo daadaa gẹgẹ bi ohun ti ofin orileede yii wi. Awọn aṣofin agba ọhun si yẹ wọn wo, lẹyin naa ni wọn fontẹ lu wọn pe wọn yege.
Awọn minisita tuntun meje naa ati ipo ti wọn di mi ninu iṣakoso ijọba Aarẹ Tinubu niwọnyi.
Dokita Nentawe Yilwatda: Minisita fun ọrọ ileṣẹẹ-wọgbẹ, Muhammadu Maigari Dingyadi, Minisita fun ọrọ iṣẹ, Bianca Odinka Odumegu Ojukwu, Minisita kekere fun ọrọ ilẹ okeere, Dokita Jumọkẹ Oduwọle, Minisita fun ọrọ okoowo, Idi Mukhtar Maiha, Minisita fun ọrọ ohun ọsin, Yusuf Abdullah Ata, Minisita fun ọrọ ile gbigbe, Dokita Suwaiba Said Ahmed, Minisita fun eto ẹkọ.
Gbogbo awọn minisita tuntun wọnyi pata ni wọn n reti pe ki wọn tete bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹu, kawọn naa le kopa pataki ninu iṣakooso ijọba Aarẹ Tinubu to wa lode bayii.