Gbogbo ohun to ba jẹ ojuṣe wa la maa ṣe pata bi asiko ba to – Aarẹ Tinubu 

Adewale Adeoye

Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ti sọ pe gbogbo ohun to ba jẹ ojuṣe oun pata loun maa ṣe, oun ko ni i ṣai ṣe awọn ohun to maa mu ilọsiwaju gidi ba orileede yii, nitori pe oun mọ daadaa pe orileede yii nilo akinkanju olori loun ṣe dije dupo aarẹ orileede yii lọdun to kọja.

O ni oun paapaa ti wa ni igbaradi lati koju gbogbo oke iṣoro yoowu to n koju iṣakoso ijọba orileede yii.

Aarẹ Tinubu sọrọ ọhun di mimọ lasiko to n ṣe ibura fawọn minisita meje tuntun rẹ l’Abuja.

Lasiko to n sọrọ nipa iṣẹ ilu ti wọn gba ni Tinubu ti gba wọn nimọran pe ki wọn gbaju mọ iṣẹ ilu ti wọn gba ni, ki wọn ma ṣe tẹti sawọn ọrọ abuku ati ọrọ ẹgan tawọn kan maa sọ si wọn lasiko ti wọn ba n ṣiṣẹ takuntakun lọwọ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘Mo ṣetan lati koju gbogbo oke iṣoro yoowu to n koju iṣakoso ijọba orileede yii, a ti bẹrẹ si i fọwọ lile mu ọrọ awọn ọbayejẹ ẹda gbogbo ti wọn n ji awọn ohun alumọọni orileede yii ko lọna aitọ bayii. A ko ni i sa kuro nidii ojuse wa rara, iṣẹ ta a gba ni, a gbọdọ ṣe e laṣeye ni. A si gba a laduura pe a maa ṣe e laṣeyọri ni. Loootọ ni nnkan ti dẹnu kọlẹ nipa eto ọrọ aje ka too gbajọba lọwọ awọn to gbe e silẹ fun wa, o fẹẹ jẹ pe ida mẹtadinlọgọrun-un owo ta a n pa wọle, gbese la fi n san pada fawọn ajọ agbaye gbogbo ti wọn ti yawo lọwọ wọn. Ni bayii, ida marundinlaaadọrin la fi n san gbese bayii, apẹẹrẹ pe nnkan ti n pada daa niyi. Pẹlu ba a ṣe n dọgbọn to o lọ, o maa too daa, a maa gbe ọkọ isakooso ijọba orileede yii de ebute ayọ laipẹ yii, bẹẹ lọkọ wa ko ni i ri saarin agbami lae. Ki i ṣe orileede Naijiria yii nikan laburu ti n ṣẹlẹ, bo ṣe n ṣẹlẹ lagbaaye naa niyi, ko sibi ti wọn ko ti ko adiẹ alẹ, aimọye nnkan lo n ṣẹlẹ lagbaaye.

Leave a Reply