Adewale Adeoye
Ọkan pata lara awọn Emir nilẹ Arewa, Sultan tilu Ṣokoto, Alhaji Sa’ad Mohamed Abubarkar 11, ti rọ awọn ọmọ orileede yii pe dipo ti wọn fi n gbe awọn olori wọn gbogbo ṣepe nla-nla bi wọn ba ṣe aṣiṣe lẹnu iṣakoso ijọba wọn, ṣe lo yẹ ki wọn fa wọn si kootu Ọlọrun Oba, ki Ọlọrun Ọba Allah si ṣe idajọ rẹ fun wọn.
Nibi eto pataki kan to waye laipẹ yii niluu Kaduna, ni Emir ti sọrọ naa di mimọ lasiko to n ba awọn eeyan sọrọ.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘‘Nibi tọrọ orileede yii gbe de bayii, adura la nilo nigba gbogbo, ko sohun meji to le yanju awọn oke iṣoro gbogbo ta a ni to kọja adura. Adura ọhun lo maa jẹ ki orileede Naijiria wa ni iṣọkan, ti gbogbo nnkan si maa pada bọ sipo gẹgẹ ba a ṣe ti fẹ.
‘’Bakan naa ni kawọn olori wa gbogbo ranti pe wọn n bọ waa jiyin iṣẹ ti wọn ṣe loke eepẹ fun Ọlọrun Ọba Allah lọjọ ikẹyin. Idi ree ti wọn ṣe gbọdọ ṣe ohun to daa fawọn araalu lasiko ti wọn wa nipo agbara.
‘’Ẹ sin Ọlọrun Ọba Allah lasiko tẹ ẹ wa laye, kẹ ẹ si fohun gbogbo le e lọwọ lati ba yin ṣe e laṣetan. Ẹ ma ṣe gba amọran odi lẹnu awọn to maa ṣi yin lọna rara, loootọ, oniruuru ipenija ni orileede wa n la kọja lasiko yii, a gbọdọ tẹra mọ adura ni gbigba ni, Ọlọrun Ọba Allah nikan lo le ba wa yanju awọn oke iṣoro ta a ni, ki kaluku wa maa lọọ gbadura lawọn ileejọsin wa gbogbo pe ki Ọlọrun Ọba Allah ba wa da sọrọ orileede yii.
Ọpọ lo n sọ pe nnkan ko bajẹ to bayii ri latigba ta a ti gba ominira, mo fẹẹ sọ fun yin pe ko sohun to n le ti ki i pada dẹrọ, adura nikan lo ku lati tẹra mọ bayii’’.
Bakan naa lo gba awọn olori wa gbogbo ninu ọrọ oṣelu lamọran pe ki wọn ṣe ohun tawọn araalu n fẹ fun wọn nitori pe ipo ti Ọlọrun Ọba gbe wọn si, ipo ẹlẹgẹ ni, ti kaluku wọn si n bọ waa sọ bo ṣe lo agbara ati ipo ta a gbe le e lọwọ lọjọ ikẹyin niwaju Ọlọrun.
O ni, ‘‘Ko si ani-ani nibẹ, kaluku wa lo maa pada sọ tẹnu fun Ọlọrun Ọba Allah lọjọ ikẹyin. Ko ni i si oluranlọwọ kankan to maa ran ẹ lọwọ, bẹẹ ni ko ni i si agbejọro kankan to maa duro fun ọ lati ba ẹ rojọ niwaju Ọlọrun. Kaluku pẹlu agbelebu rẹ ni. Idi ree tẹ ẹ fi gbọdọ ṣe ohun to daa lasiko ti agbara wa fun yin bayii. Awọn araalu ko nilo lati maa ṣepe tabi sọrọ odi sawọn alaṣẹ ijọba orileede yii rara, ki wọn fa wọn le Ọlọrun Ọba lọwọ. Ọlọrun Ọba Allah nikan lo le ṣe idajọ fun wọn bi asiko ba to.