Ọlọkada meje dero ẹwọn n’Ibadan, eyi lohun ti wọn ṣe

Ọlawale Ajao, Ibadan
Ọlọkada meje ti dero ahamọ ọgba ẹwọn Agodi, n’Ibadan bayii. Odidi ọjọ mẹsan-an lawọn mejeeje yoo lo nibẹ ko tilẹ too di pe wọn bẹrẹ si i sọ tẹnu wọn lori ẹsun to sọ wọn dero ahamọ.

Eyi ko ṣẹyin bi awọn ọlọkada ọhun ṣe lu oṣiṣẹ ẹṣọ alaabo oju popo ijọba ipinlẹ Ọyọ bii ẹni lu bàrà. Meje ninu wọn tọwọ awọn agbofinro tẹ lori iṣẹlẹ ọhun lo ti dero ahamọ ọgba ẹwọn Agodi, n’Ibadan, bayii.

Awọn ọkunrin to fara kaaṣa iya naa, Oyedepo Samuel ati Waheed Quadri, ti wọn jẹ oṣiṣẹ ajọ ijọba ipinlẹ Ọyọ to n mojuto igbokegbodo awọn ohun irinsẹ loju popo, Oyo State Road Traffic Management Authority (OYRTMA), ni wọn jiya bii alailẹnikan l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 ta a wa yii.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, Ọgbẹni Samuel ati Qadri ni wọn mu awọn ọlọkada meji kan fun ẹsun ìlòdì s’ofin irinna, wọn ni wọn fi ọkada wọn di oju ọna to yẹ ki awọn ọkọ ati alupupu maa gba kọja, wọn si pinnu lati kọ awọn arufin ọlọkada naa lọgbọn.

Ṣugbọn bi awọn oṣiṣẹ ijọba yii ṣe n gbe ọkada awọn mejeeji lọ si agọ ọlọpaa to wa l’Agodi Gate, n’Ibadan, lojiji ni wọn gburoo ọwọ ifọti lara ọkan ninu wọn. Iṣẹ ọwọ awọn ọlọkada to lọọ dena de wọn loju ọna niyẹn.

Njẹ ki wọn wẹyin lati mọ ẹni to na ọwọ ifọti olooyi naa, ọkẹ aimọye irin, àpólà igi atawọn nnkan ija mi-in lo pade lara awọn mejeeji.

Awọn májẹ̀ẹ́-ó-bàjẹ́ eeyan to n kọja lọ lasiko naa la gbọ pe wọn doola ẹmi awọn oṣiṣẹ ijọba yii ti awọn ẹruuku ọhun ko fi lu wọn pa.

Ṣugbọn bi wọn ko ṣe ku ọhun naa, wàràwéré lawọn mejeeji dero ileewosan apapandodo, ọsibitu to wa ninu ọgba sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọyọni wọn ko wọn lọ.

Amọ ṣa, ko ju wakati meji si mẹta lọ lẹyin naa tọwọ awọn ọlọpaa teṣan Ìdí-Àpẹ́, fi tẹ awọn meje ti wọn fura si gẹgẹ bii ẹni to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.

Atimọle ọlọpaa lawọn mejeeje sun mọju ọjọ keji, ko too di pe wọn gbe wọn lọ sile-ẹjọ Majisireeti to wa ninu ọgba sẹkiteriati ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ariwa n’Ibadan, lọjọ naa, ti i ṣe Ọjọbọ, Tọsidee, oṣu yii.

Ile-ẹjọ faaye gba ọkọọkan awọn oluẹjọ naa lati gba beeli ara wọn pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira. Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹtadinlogun (17), oṣu Kọkanla, ọdun yii.

Ṣugbọn niwọn igba ti ko ti si ẹni to ri eto beeli ara rẹ ṣe ninu wọn, awọn mejeeje naa ladajọ paṣẹ pe ki wọn rọ da sinu ahamọ ọgba ẹwọn Agodi, n’Ibadan, titi di ọjọ ti igbẹjọ wọn yoo bẹrẹ gan-an ni pẹrẹu.

Leave a Reply