Monisọla Saka
Minisita fọrọ ina lorilẹ-ede yii, Adebayọ Adelabu, ti ni airi itọju to yẹ, bi wọn ko ṣe maa lo awọn ohun eelo to n gbe ina kiri daadaa, atawọn ole to n ji nnkan lara opo nla to n pin ina ka, lo n fa a ti opo to n gbe ina kiri Naijiria ṣe n daṣẹ silẹ ni gbogbo igba.
Adelabu to n sọrọ lori abọ iwadii to gba lọwọ igbimọ ti wọn gbe kalẹ lati wadii opo nla to n gbena kiri to wo, lo sọrọ yii di mimọ niluu Abuja, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹfa, oṣu yii. O ni awọn ti wọn n ba nnkan jẹ lara opo to n pin ina kiri atawọn ole to n ji nnkan lara ẹ ni wọn fa gbogbo bi ina ṣe di idakureku lọdun 2024.
Minisita yii ni aisi itọju ati amojuto gidi lori ẹ, atawọn nnkan mi-in bii ole jija, lo n fa a ti ina fi n figba gbogbo bajẹ.
O waa fawọn araalu lọkan balẹ pe ijọba apapọ ti mu ọrọ naa ni ọkunkundun, wọn si ti da si i.
O ni ileeṣẹ awọn yoo ṣe agbeyẹwo abọ iwadii ti wọn fun awọn, lẹyin tawọn ba ṣe atunṣe tan lawọn yoo gbe e siwaju Aarẹ Tinubu.
Igbimọ ẹlẹni mẹfa, ti Arabinrin Nafisat Ali, ti i ṣe adari ileeṣẹ Independent System Operator (ISO), jẹ alaga fun, ti fa awọn nnkan to ṣokunfa bi opo ina naa ṣe n bajẹ leralera yọ.
O ni ohun to fa bi ina ṣe n bajẹ leralera lẹnu ọjọ mẹta yii ni bi ọkan lara awọn ohun eelo to wa lara opo to n pin ina ni ẹka Jẹbba ati Oṣogbo, ṣe gbina lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ati ohun eelo ti wọn n pe ni CT, toun naa tun gbina nibudo ti ina ti n wa niluu Jẹbba, lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii.
O ni lara nnkan ti igbimọ dabaa pe ki wọn ṣe lati le rojutuu ohun to wa nilẹ ati lati ri ọna abayọ, ni ki wọn ṣe eto ati atunṣe to yẹ laarin oṣu kan, ki wọn si ṣe afikun awọn oṣiṣẹ ti yoo wa nidii itọju awọn ohun eelo ina, ki wọn si ri i daju pe wọn n yẹ awọn irinṣẹ ti wọn ni nilẹ wo lawọn ibi to ba jẹ ẹlẹgẹ.
Alaga igbimọ yii ni awọn igbimọ sọ pe awọn aba to le ran iṣẹ wọn lọwọ, ati inawo to yẹ fun un yoo wa ninu aba eto iṣuna ọdun 2025, tabi ninu awọn eto iṣuna mi-in.