Nijọ wo ni Buhari fẹẹ gbọ ohun tawọn agbaagba ilu n wi
Edwin Clark, Pastor Adeboye, Oluṣegun Ọbasanjọ, Wọle Sọyinka, Atiku Abubakar, Afẹ Babalọla, Ayọ Adebanjọ, Balarabe Musa, ati awọn mi-in bẹẹ, o daju pe ko le jẹ gbogbo awọn yii ni wọn koriira Aarẹ Muhammadu Buhari. Ọpọlọpọ wọn lo ṣiṣẹ fun un lati ri i pe o di olori ijọba. Nipa bẹẹ, awọn yii ko le koriira rẹ debii pe wọn yoo maa fi ẹnu ba a jẹ. Nitori bẹẹ, bi awọn yii ba sọrọ, o yẹ ki Buhari gbọ ni, ko gba, ko si mu ohun ti wọn ba wi ṣẹ. Ṣugbọn Buhari ki i gbọ ohun ti awọn eeeyan yii ba sọ. Gbogbo awọn eeyan yii n pariwo kinni kan, iyẹn naa ni atunto si eto ijọba ati ofin orilẹ-ede yii, nibi ti ohun gbogbo yoo ti ṣe ri bo ṣe yẹ ko ri. Nibi ti ko ni i si iwa ẹlẹyamẹya, ti ko si ni i si ilakaka lati gbe awọn Fulani bori awọn ẹya to ku ni Naijiria. Edwin Clark lo bawọn ọmọ Ijaw la ọrọ yii mọlẹ, o ni Naijiria yoo fọ pẹkẹpẹkẹ bi Buhari ṣe n gbiyanju lati gbe awọn ara ilẹ Hausa le ori gbogbo ẹya to ku ni Naijiria, ti wọn n gba nnkan ọrọ ati ohun-ini wọn fun wọn, ti wọn si n gba ipo lọwọ awọn ọmọ Yoruba ati Ibo, ti wọn n gbe e fawọn Hausa-Fulani. Ọrọ Adeboye naa ko yatọ si bẹẹ, baba oniwaasu agbaye naa si ni ki Buhari dide, ko ṣe nnkan kan, ko ja Naijiria gba kuro ni ọna iparun to n tọ lọ yii, ki Naijiria le di nnkan nla ti gbogbo aye n reti. Ohun to n mu wọn sọrọ ko ju ti ayẹyẹ ọgọta ọdun ti Naijiria ti gba ominira ti wọn n ṣe lọ. Bo tilẹ jẹ pe ohun ẹyẹ lo yẹ ki ọrọ naa jẹ fun gbogbo ọmọ Naijiria, ṣugbọn niṣe ni ilu kan bobo, nitori ko si ọmọ Naijiria kan to ri ohun ti yoo dunnu le lori. Ṣe ti awọn ti wọn ti niṣẹ ti wọn ko niṣẹ mọ ni, tabi ti awọn ti wọn ti pa awọn eeyan wọn, tabi ti wọn ti ji awọn eeyan wọn gbe, tabi ti awọn ti wọn mọ pe inu ewu lawọn wa, ti wọn n fi ojoojumọ reti iku. Ṣe awọn yii ni yoo ṣe ayẹyẹ ọjọọbi kan. Ohun to n mu awọn agbaagba ilu sọrọ bayii ree, pe ọwọ Buhari funra ẹ lohun gbogbo wa, oun lo le tun nnkan ṣe, oun lo le sọ pe bayii loun ṣe fẹ ki Naijiria ri, ti gbogbo ọmọ Naijiria yoo si maa tẹle e. Ohun to n baayan lẹru ni pe Buhari ki gbọ iru ọrọ bayii, bo ba si gbọ, ki i mu un lo, ohun ti gbogbo nnkan ṣe dẹnukọlẹ ree o. Nigba ti gbogbo iru awọn eeyan nla bayii ba ba Buhari sọrọ ti ko gbọ, ta lo waa ku ti yoo le ba a sọrọ to fẹẹ gbọ. Abi iru ki la waa ko si yii ooo!
Igba wo ni Ọṣinbajo naa fẹẹ laya lati sọ ododo
Lara ohun to ṣi n pa ijọba Buhari yii ku ni pe ko si ẹni ti yoo ba baba naa sọ ododo ninu awọn ti wọn n ba a ṣiṣẹ. Ọkan pataki ninu awọn eeyan ti wọn ti ro pe yoo le sọ ododo taara ni Igbakeji Aarẹ funra ẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, i ṣe. Ṣugbọn awọn ọrọ ti ọkunrin naa maa n sọ nigba mi-in, ọrọ amunibinu ni. Kaka ki Ọṣinbajo ba awọn ti wọn jọ n ṣejọba sọ ootọ ọrọ, yoo maa yi ọrọ lọrun, yoo maa pọn irọ lewe fawọn araalu, yoo si fi ibi ti ọrọ wa silẹ, yoo dojukọ awọn to mọ pe wọn ko le ṣe kinni kan si i. Lẹẹmeji ọtọọtọ lọsẹ to lọ yii, Ọṣinbajo sọrọ meji: Akọkọ ni pe oun naa gba pe Naijiria le fọ si wẹwẹ, o ni ogiri ti lanu nilẹ wa, eleyii si le jẹ ki ilẹ Naijiria wo. Ṣugbọn kaka ko ba awọn ti wọn wa nidii ọrọ sọrọ pe ẹyin lẹ n fa a ti ogiri fi n lanu yii o, o ni awọn eeyan ti wọn n pariwo pe awọn fẹẹ ya kuro lara Naijiria lo fẹẹ fọ Naijiria. Ko sọrọ lori ohun ti wọn ṣe n sọ pe awọn fẹẹ kuro lara Naijiria, ko sọrọ lori ohun to n bi wọn ninu, o kan ni awọn kan fẹẹ wole mọ Naijiria lori ni. Lẹẹkeji ti yoo sọrọ naa nkọ, nitori pe awọn eeyan n pariwo pe Buhari ko ko awọn ẹya mi-in si ibi iṣẹ ijọba, awọn Fulani nikan lo n ko sibẹ, Ọṣinbajo jade, o ni ki i ṣe ẹya ni wọn fi gbọdọ yan eeyan sipo, ẹni to ba kun oju oṣuwọn, to si mọ iṣẹ bii iṣẹ ni wọn n yan sipo kan. Itumọ eyi ni pe awọn Fulani ti Buhari n yan sipo yii nikan ni wọn kun oju oṣuwọn, ko si akọṣẹmọṣẹ to mọṣẹ ninu awọn ọmọ Yoruba, ko si ẹni to mọwe ninu awọn ọmọ Ibo, afi lọdọ awọn Fulani to wa lati ọdọ awọn Buhari lọ. Ṣugbọn to ba jẹ ọmọ Yoruba lo wa nibẹ, awọn Hausa yoo pariwo pe wọn ko fi awọn si i, awọn Fulani yii yoo ti mura ija, wọn yoo si maa pariwo pe wọn fẹẹ le awọn ni Naijiria ni. Kaka ki Ọṣinbajo ran Buhari leti iru awọn nnkan wọnyi, ko sọ fun un pe ko daa ko jẹ awọn ẹya tirẹ nikan ni yoo maa ko sinu iṣẹ ijọba, o ni awọn ti wọn mọṣẹ ni Buhari n yan, ko fi ti ẹya ṣe. Ṣe ọrọ niyẹn nigboro ẹnu! Nijọ ti ijọba yii ba kogba wọle, ti nnkan si bajẹ pata, Ọṣinbajo yoo wa ninu awọn ti wọn yoo maa darukọ bii awọn aṣẹbajẹ to ba ti Naijiria jẹ, nitori nigba to yẹ ko sọ ododo fun ọga rẹ, ko wi kinni kan. Ẹyin pasitọ ijọ Ridiimu gbogbo, asiko yii lo yẹ ki ẹ wa Ọṣinbajo kan, ki ẹ sọ fun un pe ohun to n ṣe yii yoo lẹyin o, ko ma tori ohun to n ri loni-in ba ọjọ ọla rẹ ati tawọn ọmọ rẹ jẹ o.
Bi ẹ ti n ge wọn lọwọ, wọn yoo si maa bọ oruka
Ohun mi-in to fi ijọba yii han bii eyi ti ki i gbọran rara ni pe nigba ti gbogbo ilu ba n pariwo pe ohun ti wọn n ṣe yii ko daa, wọn yoo si gbe ọrọ banta kan lulẹ, ọrọ naa yoo si fi han bi ironu ati laakaye wọn ti to gan-an. Gbogbo bi a ti n wi pe ko dara ki ijọba fi owo kun owo epo mọto, nitori inira to n ba gbo araalu, ti gbogbo eeyan si n bẹ Buhari gẹgẹ bii olori ijọba yii pe ko wa nnkan ṣe si i, esi kan naa ti olori ijọba wa yoo fọ jade, esi to da gbogbo aye jokoo ni. Buhari ni ko dara ko jẹ iye ti wọn yoo maa ra epo ni Saudi Arabia yoo pọ ju iye ti wọn yoo maa ta epo ni Naiijria lọ. Bi a ti n sọrọ yii, ni Saudi Arabia, naira mejidinlọgọsan-an (N178) ni wọn n ta lita epo kan, wọn si n ta a ni ọgọjọ naira (N160) ni Naijiria, a jẹ pe iye ti wọn n ta epo ni Saudi fi naira mejidinlogun (N18) ju ti Naijiria lọ. Bi wọn ba fẹẹ tẹ le ọrọ ti Aarẹ Buhari sọ yii, wọn gbọdọ maa ta epo bẹntiroolu tọdọ wa naa ni ọgọsan-an naira, ko le ju ti awọn ara Saudi lọ diẹ. Ọrọ yii yoo fi bi ọpọlọ awọn ti wọn n ṣejọba le wa lori ti tobi to, ati bo ṣe gbeṣẹ to han gbangba. Awọn kan ni wọn kọ ọrọ ikọkukọ yii fun Buhari ko ka a jade, oun naa ko si wadii ọrọ, o gbe ohun ti wọn kọ fun un yii wa si ojutaye. Iru ifira-ẹni-ṣe-yẹyẹ wo ree, nitori niṣe ni yoo da bii pe alaimọkan ni olori ilẹ wa. Idi ni pe ni Saudi Arabia ti wọn n fi we Naijiria bayii, owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju lọ nibẹ, ẹgbẹrun lọna ọọdunrun ati mẹrin naira (N304,000) ni. Eyi ni pe ẹni to fẹẹ ra epo lita kan ni naira mejidinlọgọsan-an, ọọdunrun egbẹrun naira lo n gba loṣu. Awa ọmọ Naijiria ti wọn ni ki a waa ra epo tiwa ni ọgọjọ, ti Buhari si ni ko daa yii, pe afi ka ba ti Saudi mu, ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira loṣiṣẹ ti owo-oṣu ẹ kere ju lọ n gba. Eyi ni pe ilọpo mẹwaa owo-oṣu awọn ọmọ Naijiria ni wọn n gba ni Saudi. Bi Buhari ba fẹ ki wọn maa ta epo ni Naijiria ni iye ti wọn n ta a ni Saudi, ko ṣe e ki owo-oṣu awọn oṣiṣẹ wa ba ti Saudi mu. Abi ki lo le ninu iyẹn. Awọn ọlọpọlọ kukuru gbogbo!
Ṣebi ẹ gbọ raurau tiyẹn naa n sọ
Garba Sheu, lara awọn ti wọn n ṣi Buhari lọna, nitori pe ọkan ninu awọn agbẹnusọ rẹ ni, jade si gbangba lọsẹ to kọja pe ko bojumu lati maa fi owo-ori ti awọn Fulani onimaaluu n san gbọ bukaata awọn ara Isalẹ-Ọya (South) ti wọn n ra epo bẹntiroolu si mọto wọn. Ohun ti Garba Shehu n sọ ni pe awọn Fulani yii ko ni mọto, wọn n fẹsẹ rin kiri inu igbo ni, ko si ni i waa daa ki ijọba maa gba owo-ori lọwọ wọn, ki wọn waa lo owo-ori ti wọn ba san naa lati fi kun owo-epo mọto ti awọn eeyan kan n lo kaakiri. Akọkọ ni pe Fulani onimaaluu ki i san owo-ori! Nibo ni wọn n san an si, ta lo n gba owo-ori naa lọwọ wọn. Fulani wo lo wa nilẹ Yoruba to ni oun ni maaluu, oun n lọọ san owo-ori oun, ta ni yoo gba owo-ori bẹẹ lọwọ rẹ, ta ni awọn naa n san an fun. Ko si ohun to jọ bẹẹ, isọkusọ lasan ni. Lọna keji, awọn owo oriṣiiriṣii ti wọn n gba nilẹ Yoruba, owo-ori lori ọja, lori omi ati lori ọti, owo yii ni wọn n ko lọ silẹ Hausa ti wọn fi n ṣe gbogbo ohun to yẹ ki wọn ṣe. Ṣebi owo-ori ti wọn n gba nilẹ Yoruba ni wọn fi n kọ reluwee lọ si Nijee yii, owo-ori ti wọn n gba lori pe wọn ni Naija Delta ni wọn fi n kọ oriṣiiriṣii ohun to tọ ati eyi ti ko tọ silẹ Hausa. Nijọ wo waa ni owo Fulani onimaaluu di ohun ti wọn n pin ni Naijiria. Ọrọ were ni! Ohun to si ṣe n sọ eyi ko ju lati fi juujuu bo wa loju pe awọn Fulani onimaaluu naa n da si eto ọrọ aje ilẹ wa lọ. Bẹẹ irọ ni, agba-lọwọ-merii ni wọn, awọn ole ajẹju-olohun-lọ. Ki Fulani na owo-ori ti wọn ba n san si ilẹ Hausa, ki wọn si gba Yoruba ati Ibo naa laaye lati na owo-ori ti wọn ba n san si adugbo tiwọn. Ki kaluku na iye to ba pa, ohun ti ko fi ni i si ija niyẹn, ohun ti wọn si n pe ni atunto gan-an niyi. Ko ju bẹẹ lọ!
Ẹyin ti ẹ n ṣejọba, ẹ fi ti Babangida ṣarikọgbọn.
Igba mi-in, Ọlọrun a maa fi iku bo awọn mi-in laṣiiri, to jẹ wọn ko ni i rare, tabi ki wọn jiya ohun aburu ti wọn ba ṣe. Awọn meji kan wa ti eeyan yoo fi ṣe arikọgbọn ni Naijiria yii, ẹni akọkọ ni Arthur Nzeribe, ẹni ekeji naa si ni Ibrahim Babangida. Awọn Ibrahim Babangida ni wọn lo Nzeribe lati ba ibo ọdun 1993 jẹ, ti ọrọ si fi di ariwo kari gbogbo aye. Ọkunrin naa ti rọ lapa, to rọ lẹsẹ ka ile rẹ lati bii ọdun mẹwaa sẹyin, ẹnikan ko si gburoo ẹ nibi kan. O wa laye bii oku, Ọlọrun sọ ọ si ookun aye. O daju pe yoo ti kabaamọ gbogbo aburu ti wọn lo o lati ṣe. Ṣugbọn tirẹ ko to ti Babangida o. Ẹni to ti jẹ olori orilẹ-ede yii nigba kan, ẹni to fi odidi ọdun mẹjọ gbako ṣejọba Naijiria, ti ko si si ẹni to lagbara bii tirẹ laye ijọba ologun. Aṣẹ to ba pa ni, ohun to ba ṣe ni, ko si ẹni ti wọn bi daadaa ti yoo beere pe bawo lo ti ṣe ṣe e. Ọkunrin naa si niyi gan-an ni, gbogbo Naijiria lo fẹran ẹ nibẹrẹ, afi bo ṣe di aarin meji to bẹrẹ si i ṣiwa-hu, to si ṣiwa naa hu titi ti ijọba fi bọ lọwọ rẹ. O fagi le ibo ‘June 12’, o taku, ko gbejọba fun Abiọla to wọle ibo, wọn si fi Abiọla sinu sẹẹli titi to fi pada ku naa ni. Iye ẹni to ku lori ọrọ yii ko lonka, awọn ti wọn si ju sinu ajaalẹ ko ṣee fẹnu sọ. Bẹẹ Babangida yii lo da gbogbo ẹ silẹ. Loni-in, o wa laye, ṣugbọn aye ti kọja lori ẹ. Ara rẹ ko ya mọ, ko le rin kiri, ko le sọrọ gaara, ko si ni agbara kan ti yoo lo le ẹni kan lori. Ọsẹ to kọja lo ni oun ko le sọ itan aye oun o, nitori ibẹru, o ni awọn kan yoo pe oun lẹjọ. Eyi fi han pe ọkunrin ologun naa ko fẹran orilẹ-ede yii, nitori bo ba ṣe pe o fẹran ilẹ yii ni, niṣe ni iba kọ itan igbesi aye rẹ, ti iba si sọ ootọ to wa nibẹ pata, ti gbogbo awọn ti wọn ba n ṣejọba yoo le ri ọrọ ara rẹ fi ṣe arikọgbọn. Ṣugbọn bo ba ni oun ko kọ naa, ko ma kọ ọ, aye yoo ba a kọ itan ara rẹ, ṣugbọn bo ba ri iwe ti awọn eeyan kọ naa lọrun nigba to ba ku tan, oun naa yoo bu ṣẹkun ni. Ẹyin ti ẹ n ṣejọba, ẹ fi ti Babangida ṣarikọgbọn.