Ọrọ Yoruba kan ti wọn maa n sọ pe, ‘ọba ki i pe meji laafin’ ko fẹẹ fidi mulẹ pẹlu bi nnkan ṣe n lọ bayii ninu ẹgbẹ awọn onimọto nilẹ wa. Bi wọn ko ba si tete feegun otolo to ọrọ ọhun, afaimọ ki wahala nla ma ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ ọhun. Eyi ko sẹyin bi Alaaji Tajudeen Ibikunle Baruwa, to wa nipo olori ẹgbẹ t̀ẹlẹ naa ṣe sọ pe oun loun ṣi wa lori aga gẹgẹ bii aarẹ ẹgbẹ onimọto kaakiri Naijiria. Bakan naa si ni alaga ẹgbẹ awọn onimọto tẹlẹ nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya, ti gbogbo eeyan mọ si MC Oluọmọ, naa ti n sọ pe oun ni aarẹ ẹgbẹ ọhun, to si ti jokoo tepọn sori aga ijọba ni olu ileeṣẹ ẹgbẹ ọhun to wa niluu Abuja.
Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni awọn oloye ẹgbẹ naa nilẹ Yoruba yan MC Oluọmọ gẹgẹ bii aarẹ gbogbogboo fun ẹgbẹ onimọto, niwọn igba to jẹ pe apa ilẹ Yoruba lo kan gẹgẹ bii eto ti wọn la kalẹ.
Awọn oloye ẹgbẹ to dibo yan MC niluu Oṣogbo, nipinlẹ Ọṣun, ni ko sẹni to tun jade lati ba ọga awọn onimọto Eko tẹlẹ yii dupo naa, nidii eyi, ọnọpoosi lo wọle. Wọn ko si fi akoko ṣofo rara ti wọn fi bura fun un gẹgẹ bii aarẹ ẹgbẹ onimọto lapapọ lọjọ naa gan-an.
Ilẹ ọjọ keji mọ tai mọ ni Akinsanya ti balẹ siluu Abuja, pẹlu awọn alatilẹyin rẹ, ile-ẹgbẹ naa ni wọn lọ taara, ti ọkunrin yii si gbakoso ibẹ, bẹẹ lawọn oloye ẹgbẹ gbogbo wa nikalẹ lati ki i kaabọ.
Ṣugbọn ayọ pe MC di aarẹ awọn onimọto ni wọn n yọ lọwọ ti ikede mi-in fi tun jade pe ọkunrin naa ko lẹtọọ si ipo yii. Wọn ni bi ọba kan ko ba ku, omi-in ko le jẹ. Awọn to n sọrọ yii ko sọ ọ lasan, iwe kan ti wọn gba lati ile-ẹjọ kotẹmilọrun niluu Abuja to fọwọ si i pe wọn ko lẹtọọ lati yọ Alaaji Ibikunle Baruwa nipo aarẹ ni wọn mu jade. Wọn ni ile-ẹjọ ti fagi le ẹjọ ti wọn pe ọkunrin yii pe ko lẹsẹ nilẹ, o si ti ni ko maa ba iṣẹ lọ bii aarẹ ẹgbẹ.
Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, Baruwa sọ pe yiyan ti wọn yan MC Oluọmọ gẹgẹ bii aarẹ ẹgbẹ onimọto da bii igba teeyan n ri eto idajọ orileede yii fin ni. O ni ile-ẹjọ to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ, National Industrial Court, ti da oun lare lọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun yii, ninu ẹjọ ti oun pe ta ko awọn ọmọ ẹgbẹ kan ti fẹẹ yọ oun nipo, ti kootu si ni ki oun maa ba iṣẹ oun lọ gẹgẹ bii aarẹ ẹgbẹ onimọto kari Naijiria.
Bakan naa lo ni oun tun jare bọ nile-ẹjọ kotẹmilọrun, nitori kootu da ẹjọ naa lọjọ kẹjọ, oṣu yii, pe ki ẹnikẹni ma tu igbimọ ti Baruwa gbe kalẹ to n ṣakoso ẹgbẹ onimọto apapọ ka, ki wọn ma si di i lọwọ.
Igbimọ awọn onidaajọ ẹlẹni mẹta ti wọn gbọ ẹjọ naa ni: Onidaajọ Hamma Akawu Barka, Onidaajọ Nnamdi Okwy Dimgba ati Onidaajọ Asmau Ojuọlape Akanbi. Awọn mẹtẹẹta ni wọn fẹnu ko pe ẹjọ ti MC Oluọmọ, Alaaji Tajudeen Agbẹdẹ ati aarẹ ẹgbẹ onimọto lapapọ tẹlẹ, Alaaji Najeem Yasin, pe ko lẹsẹ nilẹ, wọn ni awọn ti fọwọ osi da a nu, bẹẹ lawọn tẹlẹ idajọ ti ile-ẹjọ to n gbọ ẹjọ awọn oṣiṣẹ, Nigerian Industrial Court da lori ẹjọ yii.
O waa rọ ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa, Kayọde Ẹgbẹtokun, ati Adajọ agba nilẹ wa, Lateef Fagbemi, lati ri i pe wọn fidi idajọ to waye yii mulẹ.
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2023, ni wọn yan Baruwa fun saa keji, lẹyin ti awọn aṣoju to yẹ lati dibo naa ṣeto idibo ọhun, ti wọn si fọwọ si si i gẹgẹ bii aarẹ ẹgbẹ naa fun saa keji. Eyi ni ko dun mọ awọn ọmọ igbimọ ẹgbẹ naa kan, ninu eyi ti Tajudeen Agbẹdẹ ati Aarẹ ẹgbẹ awọn onimọto tẹlẹ, Alaaji Najeem Yaro wa ninu, wọn ni awọn aṣoju to yan Baruwa ko tẹle ilana ati ofin ẹgbẹ.
Eyi lo mu ki awọn igbimọ to gbe Baruwa lọ si kootu naa ko awọn mi-in jọ, ti wọn si ṣeto idibo mi-in lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun to kọja, nibi ti wọn ti sọ pe Alaaji Issa Ọrẹ ni aarẹ ẹgbẹ tuntun.
Ṣugbọn Onidajọ O.O, Oyewumi dajọ lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kejọ ọdun 2023, pe awọn aṣoju to dibo yan Baruwa lẹsẹ nilẹ, wọn si tẹle gbogbo ofin ati ilana to yẹ ki wọn too gbe igbesẹ naa.
Idajọ yii ni ko tẹ awọn igun Yasin lọrun ti wọn fi gba ile-ẹjọ kotẹmilọrun lọ, ti idajọ si waye lẹyin ti igbimọ onidaajọ mẹta gbe e yẹwọ lọjọ kẹjọ, oṣu yii, pe idajọ ti ile-ẹjọ to n ri sọrọ awọn oṣiṣẹ gbe kalẹ lawọn naa tẹlẹ, wọn ni ki Baruwa maa ba iṣẹ rẹ lọ.
Ọsan-kan-oru kan, iyẹn lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun to kọja yii, ni awọn eeyan MC Oluọmọ le ọkunrin naa kuro nile ẹgbẹ wọn to wa niluu Abuja, ti Agbẹdẹ atawọn igbimọ rẹ si n dari ile-ẹgbẹ ọhun.
Ṣugbọn ọrọ ti bẹyin yọ bayii, o si ti di pe ọba meji lo n ja si ade kan ṣoṣo.
Ko sẹni to ti i le sọ boya awọn igun ti awọn eeyan gbagbọ pe o n ṣatilẹyin fun MC Oluọmọ yoo tun gba ile-ẹjọ giga apapọ lọ lori ọrọ yii.
Ṣugbọn ni bayii, idajọ ile-ẹjọ ko tẹ mi lọrun ti yẹ aga nidii MC Oluọmọ gẹgẹ bii aarẹ apapọ ẹgbẹ naa.