Ẹ gba wa o, ẹgbẹ oṣelu APC ti ko tọọgi wọ gbogbo abule to wa nijọba ibilẹ Idanre-Akíngbàsọ̀

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Igbakeji gomina fun oludije ẹgbẹ Peoples Democratic Party (PDP) ninu eto idibo gomina to n lọ lọwọ nipinlẹ Ondo, Ọnarebu Festus Akingbasọ, ẹni tọpọ eeyan mọ si ‘Fessy West’ ti fẹsun kan ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC) pe wọn ti ko ọpọlọpọ tọọgi lọ si awọn abule kan to wa nijọba ibilẹ Idanre, lati da jinnijinni bo awọn oludibo ki wọn ma le jade.

Ọkunrin to n ṣoju awọn eeyan agbegbe ijọba ibilẹ Idanre ati Ifẹdọrẹ ọhun nile-igbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja, lo kegbajare yii lẹyin to dibo tan ni Wọọdu Aládèé/Atọ́sìn, Yuniiti kẹjọ, Oke-Ìmikàn, Alade-Idanre.

Fessy West ni ori oun wu daadaa bi awọn eeyan ṣe tu yaayaa jade nigboro Idanre, ti ohun gbogbo si n lọ gẹgẹ bo ṣe yẹ, ṣugbọn awọn iroyin to n wa lati awon abule to wa lagbegbe Idanre, paapaa ni Ofosu, ko ṣee gbọ rara.

O ni, ọpọ awọn to jẹ alatilẹyim ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn ti le jade nile wọn, ti wọn si ti da jinnijinni bo awọn eeyan lainidii.

Ọnarebu ọhun ni oun ti pe awọn agbofinro titi lati fi iṣẹlẹ naa to wọn leti, ṣugbọn ṣe ni wọn fi gbigbọ ṣe alaigbọ.

Eto idibo sipo gomina lo n waye nipinlẹ Ondo lonii ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii. Bo tilẹ jẹ pe aago mẹjọ aarọ leto idibo yii yẹ ko bẹrẹ, nnkan bii aago meje lawọn oṣiṣẹ eleto idibo atawọn oludibo ti n de sawọn ojuko ibi ti eto idibo ti fẹẹ waye niluu Akurẹ ati Idanre, nibi ti akọroyin ALAROYE kọkọ ṣabẹwo si.

 

Leave a Reply