Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ Emmanuel Anthony, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, lori ẹsun igbimọ-pọ huwa buburu ati idigunjale.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe ni nnkan bii aago meji aabọ ọsan ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni Amọle Muiz ati Adegoke Gbenga, ti wọn n gbe niluu Ẹsa-Oke, lọọ fi to awọn ọlọpaa leti pe awọn agbebọn kan ti wọn wọ aṣọ ologun da awọn lọna, wọn si ji awọn gbe lọ sinu igbo.
Awọn ọmọkunrin yii ṣalaye pe mọto Honda Pilot Jeep, lawọn agbebọn naa fi gbe awọn lọ sinu igbo kan loju ọna Ekiti, wọn si sọ pe ki awọn tiransifaa miliọnu mẹta Naira sinu akaunti Monie-point kan, lẹyin naa ni wọn too yọnda awọn lati lọ.
Bakan naa ni awọn eeyan meji mi-in, Ọlawumi Oluwaṣeun ati Ishọla fi to ọlọpaa leti pe awọn agbebọn yii kan naa tun digun ja awọn lole, wọn gba iphone 12 ati iphone 13 awọn, bẹẹ ni wọn gba owo to le ni miliọnu kan Naira lọwọ awọn (#1.25m).
Lọgan ni ikọ to n gbogun ti iwa ijinigbe bẹrẹ iwadii, wọn ṣayẹwo akanti ti awọn oniṣẹ ibi yii n gba owo si, wọn si ri i pe David Agbebaku, ẹni to di mimọ pe o ti ko si pampẹ awọn ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, lo ni akaunti yẹn.
Ninu iwadii naa lọwọ ti tẹ Emmanuel Anthony, niluu Ibadan. O jẹwọ pe lẹnu iṣẹ ologun ni wọn ti le oun danu, nigba ti oun si pade David atawọn meji mi-in, tawọn naa ti figba kan ri jẹ ọmọ ologun, lawọn jọ n ṣiṣẹ papọ.
Nigba to n ba ALAROYE sọrọ, Emmanuel ṣalaye pe ọmọ bibi ipinlẹ Abia loun, inu oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni wọn si le oun danu lẹnu iṣẹ ologun latari awọn iwa aibọwọ fun awọn ọga ati titapa sofin iṣẹ ologun orileede yii ti oun hu.
O sọ siwaju pe ileeṣẹ ologun ko gba awọn aṣọ, fila, bẹliiti ati oniruuru nnkan to jẹ tiwọn lọwọ oun, idi si niyẹn ti oun fi n lo awọn nnkan naa lati fi dunkooko mọ awọn araalu.
Emmanuel fi kun ọrọ rẹ pe ṣe ni David sọ fun oun pe awọn fẹẹ gba owo lọwọ awọn ọmọ Yahoo kan, idi si niyẹn ti oun fi gba lati ṣe e.
Ọpalọla sọ pe laipẹ yii ni Emmanuel yoo foju bale ẹjọ.