Ayedatiwa wọle ibo gomina l’Ondo

Ajọ eleto idibo ilẹ wa ti kede gomina ipnlẹ Ondo to wa lori aleefa bayii, Ọgbẹni Lucky Ayedatiwa ti ẹgbẹ oṣelu All Progresive Congress (APC),  gẹgẹ bii ẹni to bori lasiko ibo gomina to waye nipilẹ naa lọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii.

Ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ naa ni Ayedatiwa ti wọle.

Nigba to n kede esi idibo ọhun, Ọga agba ileewe giga Yunifasiti ijọba apapọ to wa niluu Lọkọja, nipinlẹ Kogi, Ọjọgbọn Akinwumi Ọlayẹmi Durotimi sọ pe ayedatiwa lo wọle pẹ̀u bo ṣe ni ibo ọta le lọọọdunrun le mẹfa ati ọrin le lẹẹẹdẹgbẹrin le ẹyọ kan ibo (366,781), nigba ti Agboọla Ajayi to jẹ oludije ẹgbẹ PDP ni ibo ẹgbẹrun mẹtadinlọgọfa ati oji le lẹgbẹrin le mẹfa (117,846).

Ohun tí eto idibo yii fi yatọ diẹ ni pe iwọnba awọn eeyan perete ni wọn jade dibo, koda, nigba ti aago mọkanla aarọ yoo fi lu, ọpọlọpọ Wọọdu ati Yuniti ni wọn ti pari eto idibo ni Akurẹ, Èró, Ilaramọkin ati Igbara-Oke, ṣe lawọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo kan jokoo ti wọn n ṣere ni ti wọn.

Aṣofin to n ṣoju awọn eeyan Guusu Akurẹ ati Ariwa Akurẹ nilegbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja, Ọnarebu Abiọdun Adeṣida, sọ ni tirẹ pe ko ti i si eto idibo to dara to ti ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2024 yii, ninu itan ipinlẹ Ondo.

Bakan naa ni Kọmiṣanna fun ọrọ agbara atawọn nnkan alumọọni nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Rasaq Obe, gboriyin fawọn ajọ eleto idibo fun ọna ti wọn gba ṣeto naa.

O ni ohun gbogbo lo lọ bo ṣe yẹ ko lọ, ati pe ko si bi wọn ṣe fẹẹ ṣeto idibo ti ko ni i ni awọn aṣiṣe diẹdiẹ ninu. Obe ni ki i ṣe Naijiria nìkan leyi ti n ṣẹlẹ, koda, o ni awọn eeyan kan lorilẹ-ede Amẹrika ṣi n binu gidigidi lori eto idibo wọn to waye laipẹ yii.

Ninu ọrọ ti Gomina Lucky Ayedatiwa to jẹ oludije fun ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress sọ lo ti dupẹ lọwọ ajọ eleto idibo, to si gbosuba fun wọn lori bi wọn ṣe ṣeto naa lai si wahala rara.

Alẹ ọjọ Abamẹta, Satide yii kan naa lawọn aṣoju ajọ eleto idibo ti ko ara wọn jọ si olu ileeṣẹ wọn to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ, ti wọn si bẹrẹ kika awọn ibo ijọba ibilẹ to ti wọle sọdọ wọn.

Nigba ti yoo si fi di nnkan bii aago kan aabọ oru kọja diẹ, ibo ijọba ibilẹ mẹtala ti wọle, ti wọn si ka gbogbo rẹ, ninu eyi Ayedatiwa ti jege patapata.

Lẹyin eyi ni olori aṣoju ajọ eleto idibo, Ọjọgbọn Ọlayẹmi Durotimi, láti Fasiti ijọba apapọ to wa nipinlẹ Kogi, kede pe awọn n lọ fun aaye isinmi. O ni o tun di aago marun-un aabọ idaji ki awọn too tun pade lati ka ibo awọn ijọba ibilẹ marun-un ti awọn n reti.

Nigba to ya ni ajọ eleto idibo tun tun ikede mi-in ṣe pe eto naa ko ni i ṣee bẹrẹ mọ laago marun-un, wọn ni o di aago mejila ọsan.

Aago mejila ọsan ni wọn ka awọn ijọba ibilẹ yooku, ti Ojogbon Ọlayẹmi si pada kede Lucky Ayedatiwa gẹgẹ bii ẹni to yege ninu eto idibo ọhun pẹlu ọta le lọọọdunrun le mẹfa ati ọrin le lẹẹẹdẹgbẹrin le ẹyọ kan ibo (366,781), nigba ti Agboọla Ajayi to jẹ oludije ẹgbẹ PDP ni ibo ẹgbẹrun mẹtadinlọgọfa ati oji le lẹgbẹrin le mẹfa (117,846)

Nigba to n bawọn oniroyin sọrọ lẹyin ikede naa, Alaga ẹgbẹ All Progressive Congress nipinlẹ Ondo, Ade Adetimẹhin, ni iṣẹ takuntakun ti ẹgbẹ oṣelu APC n ṣe lo mu ki awọn eeyan ipinlẹ Ondo tun fi ibo gbe oludije wọn wọle.

O ni, ọmọ abẹ Oloogbe Rotimi Akeredolu ni Ayedatiwa, ko si si ani-ani pe ko ni i ja ireti awọn eeyan kulẹ rara pẹlu bi wọn ṣe fi ibo gbe e wọle pada.

Adetimẹhin rọ ẹgbẹ PDP lati lọọ tun ara mu, ki wọn si ṣe atunṣe si gbogbo ibi ti wọn ba ti n ṣe aṣiṣe latẹyinwa, ki wọn baa le rọwọ mu ninu eto idibo to n bọ lọjọ iwaju, nitori ti ọmọde ba ṣubu, aa wo iwaju, ṣugbọn ti agba ba ṣubu, ẹyin ni í í wo. Ṣé ikọ kan ko yẹ ko kọ agba lẹsẹ leẹmeji.

Leave a Reply