Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Igbimọ oludamọran fun mọṣalaaṣi apapọ ilu Oṣogbo, eyi ti wọn n pe ni Aláṣàrò ti sọ pe bi Imaamu agba ilu naa, Sheikh Musa Animaṣahun, ṣe fi ọkan lara awọn ọmọọṣẹ Gomina Adeleke, iyẹn Alhaji Muniru Raji, jẹ oye Aṣiwaju ilu Oṣogbo, ko ba ilana mu rara.
Olori igbimọ naa, Alhaji Sulaiman Akala, ṣalaye pe iyansipo Raji ta ko ilana, aṣa ati ilakalẹ ẹsin Islam, ti awọn gbe lọwọ.
Alhaji Akala sọ pe lọwọlọwọ, Muniru Raji ni oludamọran pataki fun Gomina Adeleke lori ọrọ ẹgbẹ oṣelu, o si digba to ba too bọ aṣọ oṣelu silẹ ki awọn too le fi i jẹ oye ẹṣin kankan.
O ni ko si ẹni to bun awọn Alaṣaro gbọ rara nipa igbesẹ naa, ṣe lawọn kan hu u gbọ pe Imaamu agba ti fi lẹta ranṣẹ si Muniru pe oun ni Aṣiwaju ilu Oṣogbo.
O sọ siwaju pe ohun to han gbangba ni pe ṣe ni awọn kan ko sabẹẹ Imaamu Agba lati huwa to hu naa, ṣugbọn awọn Alaṣaro ko ni i faaye gba ohunkohun ti yoo ba ilana ẹṣin Islam jẹ niluu Oṣogbo.
Alhaji Akala fi kun ọrọ rẹ pe lati ayebaye ni Alaṣaro ti maa n dari akoso awọn Musulumi niluu Oṣogbo, titi de ori ẹnikẹni ti wọn ba fẹẹ fi joye, ti akọsilẹ eleyii si wa ninu ofin wọn.
O waa ke si Ataọja ilu Oṣogbo, lati fi ọrọ ẹsin ilu naa silẹ fun awọn to tọ si, ko si gbaju mọ ọrọ aṣa ati ibilẹ ilu Oṣogbo.
Amọ ṣa, Sheikh Musa Animaṣahun, ti sọ pe oun ko da igbesẹ naa gbe, gbogbo Musulumi ilu Oṣogbo lawọn jọ ṣe e, o ni Imaamu lo ni aṣẹ yiyan oye ni mọṣalaaṣi Jimọh Ọja-Ọba.
O ni abẹ aṣẹ Imaamu Agba ni awọn Alaṣaro, Ratibi ati Mọgaji wa, ko si sẹni to gbọdọ ta ko igbesẹ Imaamu Agba laarin wọn, ki i ṣe awọn ni yoo paṣẹ fun Imaamu.