Ọbasanju bu epe jolẹ, ẹni ba ni ki n ku lo maa ṣaaju mi ku

Adewale adeoye

‘Kookooko lara ọta mi le, a ki i ba okunrun ẹyẹ lori itẹ. Emi o ku o, ẹni ba roku ro mi, ko maa niṣo lọrun de mi ni’. Eyi lọrọ to n jade lẹnu olori orileede yii tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, nipa ahesọ ati iroyin ẹlẹjẹ kan tawọn eeyan n gbe kiri pe baba naa ti jade laye.

Aipẹ yii ni awọn kan n gbe e kaakiri ori ayelujara pe Oloye Ọbasanjọ ti ku. Iroyin ẹlẹje naa si tan debii pe, awọn to nifẹẹ Oloye Ọbasanjọ si bẹrẹ si i kari bọnu, ti ọpọ wọn n bara jẹ, awọn mi-in tiẹ ti n daro rẹ lori ayelujara pe ẹniire ti lọ, ko too di pe awọn to sun mọ baba naa, ti wọn si n ri i lojoojumọ ṣe jade, ti wọn sọ pe ahesọ gbaa ni ohun ti awọn eeyan n gbe kiri nipa aarẹ orileede yii tẹlẹ naa. Wọn ni ko sohun to ṣe baba ti wọn tun maa n pe ni Ẹbọra Owu yii, pe alaafia ara lo wa.

Eyi lo mu ki baba naa fun awọn eeyan lesi nipa ahesọ ọhun niluu Oṣogbo, nipinlẹ Ọṣun, lasiko to n ṣi ‘Old-Garage, to wa l’Oke-Fia, lojuna Lameco, niluu Oṣogbo, eyi ti gomina ipinlẹ naa, Sẹnetọ Ademọla Jackson Adeleke, ṣẹṣẹ kọ pari.

Oloye Ọbasanjọ sọ pe, ‘’Emi paapaa gbọ nipa iroyin buruku ọhun pe mo ti ku, ori ẹrọ ayelujara ni mo ti ri i ka, loju-ẹsẹ ni mo si ti pe awọn ọmọ mi gbogbo, ẹbi ati ọrẹ pe ko soootọ nibẹ, ẹni yoowu to ba n ro iku ro mi, aa ṣaaju mi ku ni. Ọlọrun Ọba lo n daabo bo mi, ko si ni i fi mi silẹ nigba kọọkan.

‘‘Mi o mọ nnkan ti mo ṣe fun wọn ti wọn fi n ro iku ro mi, sugbọn ohun kan ti mo mọ to daju mi loju ni pe ẹnikẹni to ba n ro iku ro mi, yoo ṣaaju de ọrun alakeji’’. Bẹẹ ni Baba Iyabọ sọ.

Leave a Reply