Adewale adeoye
Fun bii wakati kan tabi ju bẹẹ lọ ni rogbodiyan nla ati idarudapọ fi waye laarin awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin agba l’Abuja, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu yii, lasiko ti wọn n jiroro lori ọrọ pataki kan. Ohun to fa wahala ọhun ko ju ijiroro kan ti Igbakeji olori ileegbimọ aṣofin agba, Sẹnetọ Jibrin Barau, gba pe ki wọn sọrọ le lori lasiko ijokoo wọn lọ.
ALAROYE gbọ pe wamu-wamu bayii lẹsẹ awọn aṣofin agba naa pe sinu ipade pataki ọhun, eyi ti Igbakeji olori ileegbimọ ọhun, Jibrin Barau, ti i ṣe ọmọ ẹgbẹ APC lati Aarin Gbun-gbun ipinlẹ Kano, to n dele fun Olori ileegbimọ aṣofin agba, Sẹnetọ Goodwill Akpabio, dari. Lẹyin ti wọn ti fọwọ si awọn abadofin kan, ti wọn si ti gba a wọle fun kika lẹẹkeji ni Sẹnetọ Ọpẹyẹmi Bamidele, to jẹ ọmọ ẹgbẹ APC lati ipinlẹ Ekiti, mu aba wa pe ki wọn gbe abadofin ti Aarẹ Tinubu gbe siwaju wọn nipa ọrọ atunṣe owo-ori yẹwo. Bẹẹ lo ni ki wọn gba oun laaye lati pe awọn onimọ nipa owo-ori wọnu ipade naa lati waa ṣalaye nipa rẹ.
Lara awọn ti wọn fẹẹ pe wọle lati waa ṣalaye nipa ọrọ owo-ori ọhun ni Ọgbẹni Tanimu Yakubu, ti i ṣe ọga agba nileeṣẹ ijọba apapọ to n ri sọrọ gbese lorileede yii, iyẹn ‘Debt Management Office’ (DMO), ati Ọgbẹni Zacch Adedeji, ti i ṣe ọga agba ẹka ileeṣẹ ijọba apapọ orileede yii to n ri sọrọ owo-ori (FIRS).
Loju-ẹsẹ ti Ọpẹyẹmi gunlẹ ni Jubrin ti kin in lẹyin pe aba naa daa gan-an ni. O sipaṣẹ fun agbọpaa ile ko pe awọn eeyan naa wọle. Ṣugbọn niṣe lawọn aṣofin kan yari, ti inu wọn ko si dun si igbesẹ naa. Wọn ni ijiroro nipa abadofin ọhun ko si ninu ohun to wa ninu iwe apilẹkọ to wa lọwọ awọn pe awọn maa jiroro le lori lọjọ naa, fun idi eyi, wọn ni ọrọ naa ti lọwọ kan abosi ninu. Eyi lo si fa a tawọn aṣofin kan ṣe fajuro gidi sọrọ abadofin ọhun.
Ọrọ naa fa idarudapọ, ti ariwo si n lọ lọtun-un losi laarin awọn aṣofin. Lara awọn ti ko fara mọ igbesẹ naa ni Sẹnetọ Ali Ndume toun naa jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣoju awọn eeyan rẹ lati Borno-South. Niṣe lọkunrin naa tutọ soke, to si foju gba a. O tọka sawọn aleebu kan to wa ninu bi wọn ṣe fẹẹ jiroro lori ọrọ owo ori naa ati bi wọn ṣe fẹe fipa pe awọn onimọ ọhun wọnu ipade pataki ọhun.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘‘Ba a fẹ, ba a kọ, awọn ohun ta a n ṣe loni-in yii maa wa ninu iwe itan, awọn araalu n wo wa nile, a gbọdọ tẹle ilana ofin to rọ mọ iṣẹ wa ni. Ko si ninu iwe apilẹkọ ti wọn fun wa pe a maa jiroro le ọrọ owo-ori naa lori loni-in, o ṣe waa jẹ pe lojiji lẹ fẹẹ gbe e wọle bayii. Ki lohun to n jo o yin lọwọ nipa abadofin ọhun, ọrọ owo-ori to wa ninu iwe abadofin naa jẹ ohun ẹlẹgẹ ta a gbọdọ ṣe suuru lati gbe yẹwo, nitori ohun to kan awọn araalu gbọngbọn ni, a ko si le ṣe e pẹlu waduwadu rara’’.
Bakan naa ni Sẹnetọ Ningi mu aba wa pe ki wọn dari awọn eeyan naa si igbimọ to n ri si ọrọ owo nina nileegbimọ lati mojuto o. O ni awọn aarẹ orileede tẹlẹ, olori aṣofin tẹlẹ, ọmọleegbimọ aṣoju-ṣofin atawọn to ti figba kan jẹ sẹnetọ nikan lofin gba laaye lati sọrọ ninu igbimọ awọn aṣofin naa.
Ṣa o, gbogbo bi Ali Ndume ṣe n sọrọ rẹ, bẹẹ ni Igbakeji awọn aṣofin agba ọhun, Sẹnetọ Jibrin Barau, n da a mọ ọn lẹnu, to si ni ko jokoo. O ni ko si asiko lati maa ṣẹṣẹ ṣe haa-in lori ọrọ naa. O paṣẹ pe ki wọn pe awọn eeyan naa wọle ki wọn waa sọ tẹnu wọn lori abadofin lori owo-ori ọhun, bo tilẹ jẹ pe eyi ko dun mọ Sẹnetọ Ndume ninu rara, to si ri igbesẹ naa bii afojudi si ipo rẹ ati aba rẹ lori ohun to n lọ naa.
Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni Aarẹ Tinubu gbe abadofin kan lọ sileegbimọ ọhun, lara ohun to wa nibẹ ni eyi ti o ti sọ pe ki awọn ipinlẹ ti wọn ba ti n rowo maa lanfaani ati ẹtọ si owo-ori ti wọn ba pa nibẹ ju awọn yooku lọ. Ko ma jẹ pe awọn ipinlẹ ti ko pawo to awọn to ṣiṣẹ owo ni yoo maa gba ju wọn lọ pẹlu awawi pe wọn pọ niye ju awọn ipinlẹ yooku lọ atawọn awawi oriṣiiriṣii bẹẹ.
Latigba ti Tinubu ti fi aba yii ranṣẹ sawọn aṣofin lọrọ naa ti n bi Ige, to n bi Adubi, pẹlu bi awọn asofin kan, paapaa awọn ti wọn wa lati Oke-Ọya, awọn gomina ati igbimọ to n ri si eto ọrọ-aje nilẹ wa, (National Economic Council) ṣe ni awọn ko fara mọ ofin naa.