Jọkẹ Amọri
Asiko yii ki i ṣe eyi to daa rara fun arẹwa Olori Ọọni Ileefẹ tẹlẹ nni, Queen Ṣilẹkunọla Ogunwusi. Eyi ko ṣẹyin bi oore ti obinrin to jẹ ajihinrere yii fẹẹ ṣe fawọn ọmọ keekeeke ṣe fẹẹ di ibi mọ ọn lọwọ.
Ni bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti fọwọ ofin mu un, wọn si ti n fọrọ po o nifun pọ lori iṣẹlẹ kan to ṣẹlẹ niluu Ibadan lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kejila yii, nibi ti eeyan bii marundinlogoji ti dagbere faye.
ALAROYE gbọ pe o ti se diẹ ti Olori Naomi ti maa n ṣeto wẹjẹ-wẹmu fawọn ọmọ keekeeke ni gbogbo ipari ọdun. O maa ko wọn jọ, yoo si fun wọn lounjẹ, wọn maa jo, wọn maa ṣajọyọ, leyin naa lo maa fun wọn ni ẹbun, ti onikaluku yoo si gba ile rẹ lọ. Obinrin yii ti sọ ṣaaju pe oun fẹran awọn ọmọde, oun si nifẹẹ ki oun maa ṣetọju awọn ọmọ to ba ku diẹ kaato fun lawujọ.
Eto yii kan naa lo gbe lọ siluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, lọjọ kejidinlogun, oṣu yii. Nipasẹ ajọ alaaanu kan to da silẹ to pe ni WINGS FOUNDATION, lo fi gbe eto naa kalẹ. Wọn ti ṣe gbogbo eto to yẹ kalẹ, wọn si ti polongo eto yii lori redio. Bẹẹ lo jẹ ileeṣẹ Redio Agidigbo ni ileeṣẹ redio ti wọn ti jọ lajọsọ ọrọ lati polongo eto yii fun wọn.
Gẹgẹ bii ohun ta a gbọ, aago mẹwaa lo yẹ ki eto naa bẹrẹ, aago meje aarọ ni awọn to fẹẹ ṣeto naa si ti ni adehun pẹlu awọn ileesẹ ọlọpaa pe ki wọn wa sibẹ lati pese aabo to to. Ṣugbọn nitori pe wọn ti sọ fun wọn pe wọn maa mu nọmba ni, ti awọn to gbe eto naa kalẹ si ti sọ pe awọn ko fẹ ju eeyan ẹgbẹrun marun-un lọ, lati aago marun-un idaji ni awọn obi pẹlu awọn ọmọ wọn kan ti gba ileewe naa lọ.
Nibi tọrọ naa si ka wọn lara de, awọn mi-in ti de lati alẹ, iyẹn o ku ọla ti eto naa maa bẹrẹ.
ALAROYE gbọ latẹnu awọn tọrọ naa ṣoju pe nigba ti ọrọ naa ka awọn eeyan wọnyi lara, niṣe ni wọn ja geeti ọgba ileewe naa, ti ọpọ wọn si rọ wọle. Ṣugbọn nibi ti wọn ti n ṣe waduwadu ni awọn kan ti n ṣubu, ti awọn mi-in si n tẹ awọn to ṣubu yii mọlẹ, ki ẹnikẹni si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, awọn kan ti ku, ọpọ si ti fara pa.
Oju-ẹsẹ ni wọn sare gbe awọn to fara pa lọ sileewosan, bii eeyan mejilelogoji lo si ti jẹ Ọlọrun nipe laarin ka diju ka la a.
Ohun to buru ni pe eto ọhun ko tilẹ ti i waye rara ti gbogbo akọlukọgba to mu ẹmi lọ yii fi waye. Alaga ileeṣẹ Redio Agidigbo, Oriyọmi Hamzat ṣalaye pe nigba ti oun ri ohun to n ṣẹlẹ ati bi ero ṣe n ya lọ sibi gbọngan ti eto naa ti fẹẹ waye loun n pariwo lori redio pe ki ẹnikẹni ma lọ si Baṣọrun Islamic College, ti eto ọhun ti fẹẹ waye mọ, ṣugbọn ti wọn ko dahun. O fi kun un pe imọtara ẹni nikan ati ojukokoro lo ṣakoba fun ọpọ awọn to lọ sibẹ. Ọkunrin na ni bi awọn ṣe n gbiyanju pati gbe awọn to ṣubu ti wọn ti tẹ mọlẹ dide ni awọn mi-in tun n sare wa, ti wọn si n tẹ awọn to ti ṣubu silẹ yii mọlẹ.
Nigba to n fidi mimu ti wọn mu Olori Ogunwusi mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Adewale Oṣifẹsọ, sọ pe loootọ lawọn ti fọwọ ofin mu arẹwa obinrin naa. O fi kun un pe ki i ṣe oun nikan ni awọn mu, o ni awọn tun fọwọ ofin mu awọn mẹfa mi-in. Awọn eeyan naa ni ọga agba patapata fun ileewe naa, Fasasi Abdullahi, Genesis Christopher, ẹni ọdun mẹrinlelogun (24), Tanimọwọ Mọrufu, ẹni ọdun mejilelaaadọta (52), Aniṣọlalaja Ọlabọde, ẹni ọdun mejilelogoji (42), Idowu Ibrahim, ẹni ọdun marundinlogoji (35), ati Abiọla Oluwatimilẹyin, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25).
Iwadii awọn agbofinro ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.