Nitori ohun to ṣẹlẹ n’Ibadan, Hamzat Oriyọmi dero ileewosan

Ọrẹoluwa Adedeji

Ba a ti n sọ yii, ileewosan kan ti wọn ko darukọ ni Oludasilẹ ileeṣẹ redio Agidigbo to wa niluu Ibadan, Alagba Hamzat Oriyọmi, wa bayii. Nibi t’ọrọ naa le de, ALAROYE gbọ pe niṣe ni ọkunrin naa daku, ti ko si ti i laju saye di ba a ṣe n sọ yii.

Aisan ojiji to kọ lu Oriyọmi naa ko sẹyin iṣẹlẹ buruku kan to ṣẹlẹ niluu Ibadan, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu yii, nibi ti awọn ọmọ bii mejilelọgbọn ti jẹ Ọlọrun nipe lasiko ti wọn n duro de Olori Naomi Ogunwusi to fẹẹ wa sibẹ lati ṣe ọdun Keresi fun wọn, ko si fun awọn to ku diẹ kaato yii lẹbun, kawọn naa le fi ni imọlara ti awọn ẹlẹgbẹ wọn to to fun lawujọ.

ALAROYE gbọ pe aago mẹwaa aarọ ọjọ yii ni wọn fi eto ti wọn ti kede lori redio naa si, ṣugbọn lati aago marun-un aarọ ni awọn ero ti n ya bii omi lọ si ileewe Baṣọrun Islamic High School, ti eto ọhun ti fẹẹ waye. Nibi ti wọn si ti n jijagudu lati to siwaju, ki ohun ti wọn fẹẹ pin fun wọn naa le kan wọn ni wọn ti n ti ara wọn, ti awọn to ku si n tẹ awọn to ṣubu yii pa.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa ko too di pe o waa pada di ero ileewosan, Oriyọmi ṣalaye fun ẹnikan pe oun ko mọ bi ara oun ṣe ri, oun ko si le sọ bi o ṣe n ṣe ohun. Ọkunrin to gbajumọ pẹlu eto rẹ ti wọn ti maa n gbe ẹnu si mic naa sọ pe ihooho loun de ile oun lọjọ iṣẹlẹ yii, ati pe awọn ọlọpaa ti wọn n gba foonu lọwọ awọn eeyan ni ko jẹ ki wọn ya aworan ihooho oun, bẹẹ lo ni o ṣee ṣe ki awọn eeyan ri aworan oun laipẹ rara.

Ọkunrin toun naa maa n ṣaanu awọn ọmọdẹ ati agbalagba lori eto tẹ yii sọ pe awọtẹlẹ pata, nikan lo ku si idi oun, niṣe ni oun si bẹrẹ si i sunkun nigba ti oun ri oore ti Olori Naomi yii feẹ ṣe, ti wọn si sọ ọ di ibi mọ ọn lọwọ. Ọkunrin naa ni bii ọmọde loun ṣe n hu, ati pe awọn agbofinro to wa nibẹ lo n rẹ oun lẹkun pe ki oun ma sunkun mọ.

Oriyọmi ni, ‘’Mo mọ ipo ti mo wa bi mo ṣe n sọrọ yii, mo mọ ohun ti mo la kọja. Ihooho ọmọluabi ni mo lọ sile lanaa, lẹyin boxer, ko si aṣọ kankan lara mi mọ. Bii ọmọde ni mo ṣe n sunkun, awọn ọlọpaa ni wọn n rẹ mi lẹkun. Awọn ni wọn gba foonu lọwọ awọn eeyan tẹ o fi ti i maa ri fọto ihooho mi nita.

‘’Mo ni awọn to subu yii, ẹ jẹ ka gbe wọn, mo si n gbe wọn, awọn ti wọn ko ṣubu si tun n sa wa si iwaju, wọn tun n tẹ wọn mọlẹ.

‘’Mo tun lọ sori redio lati lọọ pariwo pe ẹbun ti wọn fẹẹ fun wọn ko nitumọ, wọn kan fẹ kawọn ọmọ dunnu ni, mo sọ eyi ki wọn le pada, ṣugbọn oju kokoro ati iwa buru awọn eeyan ko jẹ ki wọn gbọ.

Aago meje ni awọn ọlọpaa ti a n reti yẹ ki wọn de, ṣugbọn lati aago marun-un aarọ ni wahala naa ti bẹrẹ.

 

‘’Aanu obinrin naa ṣe mi gan-an, aanu ara temi gan-an ṣe mi’’.

O jọ pe lẹyin alaye ti Oriyọmi ti kọkọ ṣe yii ati gbogbo awọn ohun to la kọja lo mu ki ọkunrin naa daku, eyi to sọ ọ di ero ileewosan bayii.

Adura ni awọn eeyan n gba pe ki Ọlọrun tete mu okunrin tawọn eeyan maa n gbadun eto rẹ daadaa yii lara da.

Leave a Reply