Adewale adeoye
‘Ko sibi ti iṣe ko si, ko sorileede kankan lagbaaye lasiko yii, titi kan orileede Gẹẹsi ati Amerika, ti ko si talaka nibẹ, kaluku wọn n dọgbọn si i ni. Ki i ṣe nitori pe iya tabi oṣi wa laarin ilu lo jẹ kawọn araalu kan padanu ẹmi wọn lojiji lasiko ti wọn n ṣe waduwadu nibi ounjẹ iranwọ tawọn ẹlẹyinju aanu kan n pin lọsẹ to kọja yii’. Eyi lọrọ to jade lẹnu Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila, ọdun yii, lasiko itakurọsọkan to ṣe pẹlu awọn oniroyin kan, ‘Media Chat,’ eyi ti ileeṣẹ tẹlifiṣan ijọba apapọ orileede yii, Nigerian Television Authority (NTA), ṣe agbatẹru rẹ niluu Eko.
ALAROYE gbe iroyin ọhun jade pe awọn ọmọde bii ogoji ni wọn ku lasiko ti wọn n ṣe waduwadu nibi ounjẹ iranwọ tawọn ẹlẹyinju aanu kan n pin fawọn araalu niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja yii. Nigba to si fi maa di ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yii kan naa, awọn araalu mẹwaa mi-in ni wọn tun ku ni ṣọọṣi ‘Holy Trinity Catholic Church’, to wa lagbegbe Maitama, l’Abuja, lasiko ti wọn n ṣe waduwadu nibi ounjẹ iranwọ tawọn kan n pin. Bakan naa lawọn bii mẹtadinlogun tun ku niluu Okija, nipinlẹ Anambra, lasiko ti wọn n jijadu nibi ounjẹ iranwọ tawọn kan n pin. Awọn iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun lo jẹ kawọn araalu maa sọrọ sawọn alaṣẹ ijọba orileede yii pe wọn ko ri ojutuu si iṣoro to n koju orileede yii lọwọ.
Lara awọn to sọko ọrọ sijọba apapọ ni ẹgbẹ oṣelu ‘African Action Congress’ (AAC), ẹgbẹ oṣelu ‘People Democratic Party’ PDP, atawọn ẹgbẹ oṣelu mi-in lorileede yii. Ohun tawọn ẹgbẹ naa n sọ ni pe o ti han gbangba pe iya ati iṣẹ gidi lo n jẹ awọn araalu lọwọ bayii.
Eyi ni Aarẹ Tinubu n fesi si to di sọ pe ọrọ tawọn ẹgbẹ oṣelu ọhun sọ ki i ṣe ootọ rara. O ni koko ohun to fa a tawọn araalu ṣe n ku lasiko ti wọn n ṣe waduwadu nibi ounjẹ iranwọ tawọn kan n pin ni pe awọn to ṣe agbatẹru eto naa ko ṣeto aabo to daa fawọn ti wọn pe ni.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘‘O daa keeyan maa ṣe itọrẹ aanu nigba gbogbo, emi paapaa maa n fawọn eeyan ni nnkan bii ounjẹ atawọn nnkan mi-in, koda mo maa n fowo tọrẹ nile mi ni Bourdilion, niluu Eko, o si ti le lọdun mẹẹẹdọgbọn bayii ti mo ti n ṣe eyi. Ko sẹni to ṣe waduwadu debii pe ẹmi maa bọ lasiko ti mo ba n ṣe itọrẹ aanu ọhun. Eto gidi wa nile ka a too bẹrẹ si i ṣe e. iwọnba awọn to mọ ni wọn le royin, mi o ni pupọ o, ṣugbọn niwọnba ti mo ni, mo n ṣe eyi ti agbara mi ka.
‘’Gbogbo orileede lagbaaye, koda, ko yọ orileede Amẹrika ati orileede Gẹẹsi silẹ, awọn talaka naa wa laarin ilu wọn. Lorileede Gẹẹsi, awọn tiẹ ni ile ounjẹ nla, nibi tawọn talaka ti wọn jẹ ọmọ oniluu ti maa n lọọ gba ounjẹ nigba gbogbo. Ohun ti tiwọn fi yatọ ni pe, wọn leto, wọn ki i ṣe waduwadu debii pe awọn kan aa wa tẹ ara wọn pa patapata. Ṣe ni wọn aa to sori ila, bi ko ba kan ẹ, o ko ni i lọ sibẹ’’. Bẹẹ ni Aarẹ Tinubu sọ.