Adewale Adeoye
‘Ba a ba ju abẹbẹ soke nigba igba, ibi pẹlẹbẹ kan naa lo maa fi lelẹ, dandan ni ki atunṣe ati atunto de ba ọrọ owo-ori tuntun ti mo gbe siwaju awọn aṣofin agba l’Abuja yii. O jẹ ọna kan gboogi ta a fi le yanju ajaga tawọn oyinbo alawọ funfun ta a gba ominira lọwọ wọn gbe si wa nigbaaya lati ọjọ pipẹ sẹyin bayii’’. Eyi ni alaye ri Olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ṣe faọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila, ọdun yii, niluu Eko.
Bẹ o ba gbagbe, latigba ti Tinubu ti gbe eto owo-ori tuntun ọhun siwaju awọn aṣofin agba l’Abuja, ni oniruuru awuyewuye ti n lọ nipa rẹ, ti ọpọ ninu awọn aṣofin ti wọn jẹ ẹya Hausa, si n ta ko abadofin ọhun pe akoba nla gbaa lo maa jẹ fawọn l’Oke-Ọya, bo ba le kẹsẹ jari.
Ọrọ naa le debii pe ijiroro nipa eto ọhun to yẹ ko waye lọjọ kẹta, oṣu Kejila, ọdun yii, ko le waye mọ, nitori ti awọn aṣofin mọkandinlogun kan ti wọn wa lati Oke-Ọya lawọn ko ni i gba pe ki ijiroro ọhun waye lọjọ ti wọn fi i si.
Ṣa o, awọn ẹya Ibo atawọn ẹya Yoruba ko rohun to buru ninu eto owo-ori tuntun ọhun rara. Ọpọ ninu awọn aṣofin agba l’Abuja ti wọn jẹ ẹya Yoruba ati Ibo ni wọn lawọn fara mọ abadofin ọhun.
Ọpọ awọn aṣofin ni wọn fara mọ atunto owo-ori yii, yatọ si Seneto Ali Ndume atawọn aṣofin kan, ati Gomina ipinlẹ Borno, Babagana Zulum, toun naa ba awọn oniroyin ileeṣẹ BBC ede Hausa sọrọ pe akoba nla gbaa lọrọ naa maa jẹ fawọn ara Oke-Ọya. O ni nitori pe ọdọ awọn ni iṣẹ ati iya pọ si ju lọ lorileede yii.
Nigba to maa fi di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ẹgbẹ awọn gomina l’Oke-Ọya naa fohun ṣọkan, wọn lawọn naa ta ko abadofin ọhun patapata ni. Ninu ipade pataki kan to waye nipinlẹ Kaduna, ni wọn ti fẹnu ko, ti wọn si rọ awọn aṣofin ti wọn jẹ ẹya wọn ti wọn wa nileegbimọ pe ki wọn dibo ta ko abadofin ọhun.
Ṣa o, Aarẹ Tinubu ti ni eto owo-ori tuntun ọhun ko ni ipalara kankan fawọn mẹkunnu rara, ati pe ọna kan gboogi lati le jẹ ki wọn pa owo sapo ijọba leto naa wa fun.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘‘Ko sohun ti ẹnikan le ṣe si i, eto owo-ori tuntun ọhun maa waye dandan ni. A ko le maa ṣe nnkan kan naa nigba gbogbo, ka maa waa reti esi ọtọ, aye ti sun siwaju kọja ibi ta a wa yii, a gbọdọ ja ara wa gba lọwọ awọn oyinbo alawọ funfun ta a gba ominira lọwọ wọn. Nnkan ti yatọ si bi wọn ṣe foju wo o nigba naa lọhun-un.
‘’Bẹẹ ko si ba a ṣe maa ṣe e, awọn araalu kan aa pariwo pe ko tẹ awọn lọrun ni. Ẹda ko le tẹ gbogbo araye lọrun lae. Awọn ọbayejẹ ẹda ti wọn n jẹ nidii iwa ibajẹ naa lo maa n pariwo ju. A ko faye ni awọn mẹkunnu lara rara, ohun ta a fẹẹ ṣe ni pe ka wa ọna to ba ofin mu, lati pa owo sapo ijọba, ki owo naa le ṣee pin daadaa. Ọgbọn ti wọn n da ni pe wọn fẹẹ fi akoko ṣofo lori ọrọ naa ni wọn ṣe n sọ pe ka ṣe suuru. Afojusun emi ni pe, olori gidi gbọdọ tete ṣohunkohun to ba ni lọkan lasiko to ba fẹẹ ṣe e ni’’.
Nigba to n dahun ibeere ti wọn bi i nipa owo iranwọ epo bẹntiroolu ti Aarẹ Tinubu yọ kuro ni kete to depo aṣẹ, eyi tawọn araalu kan sọ pe o ṣokunfa bi nnkan ṣe le koko bii oju ẹja niluu lasiko yii.
Aarẹ Tinubu ni, ‘Mi o kabaamọ fohun ti mo ṣe yii rara, o ṣe pataki pupọ fun wa lati yọwo iranwọ ọhun. Nnkan aburu ti ṣe ọrọ-aje orileede yii lasiko ta a wọle, eyi to le ṣakoba fun awọn ọmọ ti wọn ko ti i bi lorileede yii. Oke iṣoro ti wọn si maa koju lọjọ iwaju ti a ko ba yọwo iranwọ ọhun aa kọja afẹnusọ. Nnkan ti n daru mọ wa lọwọ lorileede yii nipa owo iranwọ lori epo bẹntiroolu ta a n san fawọn alagbata, a ko kọbi ara si i ni. Mi o kabaamọ lori bi mo ṣe yọwo iranwọ ọhun. A ki i ṣe Baba Keresi rara, awa la n sanwo iranwọ lori epo bẹntiroolu fawọn alagbata ọja epo, awọn orileede to sun mọ wa gbogbo ni wọn n jẹ anfaani ọhun. Eyi ko yẹ ko ri bẹẹ rara. A gbọdọ mọ koko ibi ta a n nawo wa si ni, gbese gidi lawọn ti iṣaaju ti jẹ silẹ de wa, ọgbọn la gbọdọ fi ṣe e’’ Bẹẹ ni Aarẹ salaye.