Ileepo MRS dowo pọ pẹlu ileefọpo Dangote lati maa ta epo ni ẹdinwo kaakiri Naijiria

 Monisọla Saka

Ileeṣẹ ifọpo Dangote, iyẹn Dangote Refinery, ti kede pe awọn ti ni ajọsọ ọrọ ati ifọwọsowọpọ pẹlu ileepo MRS, kaakiri orilẹ-ede Naijiria, lati maa ta bẹntiroolu fawọn eeyan ni ojileniẹẹdẹgbẹrun o din Naira marun-un (935).

Anthony Echiejina, ti i ṣe agbẹnusọ ileeṣẹ ifọpo Dangote, lo kede ọrọ yii. Wọn ni iye owo tuntun tawọn fẹ maa ta a yii ti fẹsẹ mulẹ nipinlẹ Eko, ati pe lati ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila yii lọ, ni yoo kaari awọn ipinlẹ to ku lorilẹ-ede Naijiria.

O ni awọn gbe igbesẹ yii lẹyin ti iye owo ti wọn n ta epo lati ibudo ifọpo ja walẹ lati ẹgbẹrun kan din Naira mẹwaa (990) si ẹgbẹrun kan din ọgbọn Naira (970).

Aliko Dangote, to jẹ olori ileeṣẹ Dangote ti ile ifọpo Dangote wa labẹ ẹ naa gboṣuba nla fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, fun ipa rere ti eto ki wọn maa fi owo Naira sanwo epo rọbi ni lori eto ọrọ-aje ilẹ wa.

O ni eto yii lo fa a ti ẹdinwo ṣe wa lori iye ti wọn n ta bẹntiroolu bayii.

O ni lati ri i daju pe ẹdinwo tawọn ṣe de ọdọ gbogbo araalu, awọn ti dowo-pọ pẹlu ileepo MRS, lati maa ta bẹntiroolu ni ẹẹdẹgbẹrun Naira ati ogoji o din marun-un, (935) ni gbogbo ileepo wọn kaakiri ilẹ Naijiria.

“Anfaani Naijiria atawọn ọmọ Naijiria ni ileeṣẹ ifọpo Dangote jẹ. A o tubọ maa fọwọsowọpọ pẹlu awọn tọrọ kan lati maa pese ojulowo epo bẹntiroolu fun yin lowo ti go gara.

“Erongba wa ni lati ri i pe gbogbo ọmọ Naijiria n ri epo bẹntiroolu gidi, ti ki i ṣe pe yoo wulo fun mọto wọn nikan, amọ fun ilera wọn ati apo wọn paapaa”.

Bakan naa ni Dangote rọ awọn alagbata epo yooku, titi kan ile epo NNPC, lati da si akitiyan ọhun, kawọn ọmọ Naijiria le jẹ anfaani ojulowo epo ni owo taṣẹrẹ.

Tẹ o ba gbagbe, igbesẹ Dangote yii waye, lẹyin ti wọn ṣe adinku iye ti wọn n ta epo si ẹẹdẹgbẹrun Naira o din aadọta Kọbọ (889.50) lati ẹgbẹrun kan din ọgbọn Naira (970), fawọn alagbata  ti yoo loodu rẹ nibudo ifọpo wọn lọsẹ to kọja.

Ṣaaju akoko yii ni awọn igbimọ alaṣẹ, Federal Executive Council (FEC), labẹ ijọba Tinubu, ti fontẹ lu tita epo fawọn ileefọpo ni owo Naira ninu oṣu Kẹsan-an, ọdun yii.

Eto sisan owo epo rọbi pẹlu Naira to ti bẹrẹ lati ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, lo ti tubọ ro owo Naira lagbara si i, ti adinku si ba gbogbo agbara ti wọn gbe le owo Dọla lori.

 

Leave a Reply