Wọn yoo dibo ni Western Region ni 1965. Dandan ni. Ko si Yẹkinni kan to le yẹ ẹ, ko si si Dauda kan to le da a pada sẹyin, dandan ni. Idi ni pe ọdun naa ni yoo di ọdun karun-un ti awọn aṣofin tuntun ti wa ni Western Region yii, lọdun ti Oloye Samuel Ladoke Akintọla bẹrẹ ijọba rẹ tuntun gẹgẹ bii olori ijọba West. Lati ọdun 1954 ni Ọbafẹmi Awolọwọ ti ṣe ijọba tirẹ, to si ṣejọba naa titi di ọdun 1959. Ni 1959, wọn ṣeto idibo mi-in, Awọlọwọ ni oun ko fẹẹ lọ fun saa keji gẹgẹ bii olori ijọba West, nitori awọn iṣẹ ti oun fẹẹ ṣe ni ilẹ Yoruba, oun ti pari rẹ, oun si ti fi apẹẹrẹ ati ipilẹ ti awọn to n bọ lẹyin oun yoo maa tọ lelẹ, ati pe niwọn igba to ba ti jẹ ẹgbẹ oṣẹlu awọn naa lo n ṣakoso ipinlẹ naa, ko si kinni kan ti yoo daru ni West, iṣẹ idagbasoke yoo maa ga si i lojoojumọ ni. Awolọwọ ni oun ko duro ni West mọ.
Nibo ni Awolọwọ fẹẹ lọ, oun naa fẹẹ lọọ di olori ijọba apapọ ni, o fẹẹ di olori Naijiria ninu ibo 1959, ṣugbọn nigba ti wọn dibo naa tan, oun kọ lo wọle, awọn Tafawa Balewa ati ẹgbẹ oṣẹlu wọn, NPC lo wọle. Ṣugbọn ko too di igba naa ni Awolọwọ ti fa ijọba West le ẹni to jẹ igbakeji rẹ tẹlẹ, iyẹn Oloye Akintọla lọwọ, oun si di olori ijọba lati 1960, o si n ṣejọba naa lọ. Laarin meji ni ija de ninu ẹgbẹ oṣelu AG to ko gbogbo wọn pọ, n lẹgbẹ ba fọ. Akintọla lọ ninu ẹgbẹ, o si ko awọn kan dani, awọn miiran si duro ti Awolọwọ ninu ẹgbẹ AG. Ija naa ṣi n lọ lọwọ nigba ti wọn fẹsun kan Awolọwọ, wọn lo fẹẹ fi ibọn gbajọba, wọn si ju u sẹwon. Awọn ọmọ ẹyin rẹ nigbagbọ pe Akintọla ati awọn ọrẹ rẹ tuntun to ṣẹṣẹ ni ni ilẹ Hausa lo ditẹ yii mọ Awolọwọ, wọn si pinnu lọkan ara wọn pe awọn yoo le Akintọla yii kuro nile ijọba.
Ṣugbọn gbogbo bi wọn ti gbiyanju to, kinni naa ko ṣee ṣe fun wọn, nitori Akintọla ti ba awọn ẹgbẹ NCNC ṣọrẹ, o si ti di aṣaaju ẹgbẹ naa nile-igbimọ wọn, Rẹmi Fani-Kayọde ṣe igbakeji rẹ, wọn si jọ n ba ere aniyan wọn lọ. Ọwọ awon ọmọ ẹyin Akintọla ati tawọn oloṣelu NCNC ni Western Region ni ijọba wa fun igba pipẹ, ti Akintọla si jẹ olori wọn. Nigba ti Akintọla tun woye pe awọn NCNC fẹẹ maa halẹ mọ oun, wọn ko si fẹẹ gba oun ni ọga, bo tilẹ jẹ oun ni olori ijọba, wọn n halẹ mọ oun nitori pe awọn ni wọn gbe oun wọle nijọsi, nigba naa lo wa ọna, to si fọ ẹgbẹ NCNC yii, o si mu Fani-Kayọde ati awọn to tun jẹ alagbara ninu wọn, o ni ki awọn lọọ da ẹgbẹ tawọn silẹ, wọn si da ẹgbẹ yii silẹ, wọn pe orukọ rẹ ni Ẹgbẹ Dẹmo. Ẹgbẹ Dẹmọ yii lo si ku ti Akintọla fi n ṣẹjọba West.
Inu awọn ọmọlẹyin Awolọwọ ko dun rara si gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yii, awọn AG ti wọn ti jẹ alagbara ni West tẹlẹ si ti pada di ọmọ ẹyin, eleyii mu ibinu buruku ba wọn, wọn si n wa ọna lati ri i pe awọn gba ipo awọn pada lọwọ Akintọla. Awọn ralẹralẹ NCNC to ku naa binu Akintọla, wọn ni o lo awọn tan, o sọ awọn nu, o fọ ẹgbẹ awọn ni West, o fi ẹgbẹ tirẹ rọpo tawọn, bẹ lo ko awọn opomulero inu ẹgbẹ awọn sa lọ. Awọn naa mura ija pẹlu rẹ, pe nigbakigba ti ibo ba de, awọn yoo jẹ ko mọ pe ẹran to yi ni i jẹ namọ.Nitori ẹ lo ṣe jẹ pe nigba ti ibo de ni 1964, ti wọn fẹẹ dibo lọ sile-igbimọ aṣofin apapọ, awọn NCNC darapọ mọ AG ni West, wọn fẹẹ kọ Akintọla lọgbọn. Ṣugbọn Akintọla sare ko ẹgbẹ Dẹmọ rẹ lọọ ba Sardauna, awọn naa jọ ṣe aṣepọ, nigbẹyin, awọn ni wọn wọle, wọn si sọ AG at NCNC si kolombo.
Gbogbo eleyii ti ṣelẹ, o si ti ba ọdun 1964 lọ, ọdun tuntun ni wọn wa yii, ọdun 1965, asiko si ti to ni West lati dibo mi-in, nitori ọjọ awọn aṣofin ti pe, asiko wọn ti to, ofin ko ṣaa gba wọn laaye lati lo ju ọdun marun-un lọ. Ọdun marun-un ti wọn lo yoo pe ni 1965 yii, bi wọn yoo ba si maa ṣe ijọba lọ, wọn gbọdọ dibo mi-in. Ibo yii ni gbogbo eeyan ti waa fi ọkan si pe wọn yoo fi rẹyin Akintọla wayi. Idi ni pe ibo Western Region ni, ki i ṣe ibo apapọ, awọn oloṣelu West nikan ni yoo dibo naa, ẹgbẹ mẹta lo si lagbara ju nibẹ, ẹgbẹ AG, NCNC ati ẹgbẹ Dẹmọ. Awọn ẹgbẹ AG at NCNC ti jo ṣe aṣepọ tẹlẹ, o si tun da bii pe ibo to n bọ yii naa, aṣepọ yii ni wọn tun fẹẹ ṣe. Bi wọn ba ṣe aṣepọ ibo yii, a jẹ pe ibi ti Akintọla yoo sa gba yoo le diẹ, nitori awọn meji ni yoo dawọ jọ le oun nikan lori, bi yoo si ti ja ajabọ laarin wọn yoo ṣoju gbogbo wọn.
Awọn ẹgbẹ AG ti mọ pe ibo kan ṣoṣo naa to tun ku fawọn ti awọn fi le bọ ninu oko ẹru Akintọla ati ti awọn Fulani ti wọn n ṣejọba niyi, pe afi ki awọn wọle ibo naa ṣaa ni. Bi wọn ba wọle ibo yii, ẹgbẹ Action Group wọn yoo gbajọba, olori ẹgbẹ naa ti i ṣe Dauda Adegbenro yoo si di Pirẹmia, olori ijọba fun Western Region. Bi Adegbenro ba di Pirẹmia, ko ni i ṣoro lati ba awọn ijọba Eastern Region ati ti Mid-West sọrọ lati ri i pe ijọba apapọ yọ Awolọwọ jade ni ọgba ẹwọn ti wọn fi i si. Bi Awolọwọ ko ba jade, ko si ohun ti ẹgbẹ AG le ṣe. Ibo kan naa ti wọn ni niyi, ibo 1965, bi wọn ko ba si ti wọle ibo naa, ohun gbogbo bajẹ niyi. Iyẹn ni pe Awolọwọ yoo lo iye ọdun ẹwọn rẹ pe niyi, nitori ọdun mẹwaa ni wọn sọ ọ si, awọn ti wọn ba si fi ibo gbe wọle ni 1965, wọn yoo wa nibẹ titi di 1970 ti yoo tun dibo tuntun.
Akintọla funra rẹ mọ eleyii, o si mọ pe ko si ọna mi-in fun oun paapaa ju ki oun wọle ibo 1965 yii lọ. O mọ pe loootọ ni ẹgbẹ Dẹmọ wa ninu awọn to wọle lasiko ibo 1964 sile aṣofin apapọ, bi awọn ko ba wọle ninu ibo ti 1964 ni West, agbara yoo bọ lọwọ awọn, oun yoo si padanu ipo oun gẹgẹ bii olori ijọba. Bi eleyii ba ṣẹlẹ lasiko naa fun Akintọla, ko si ohun aburu mi-in to tun ju bẹẹ lọ fun un. Itiju naa yoo pọ ju abuku lọ fun un, nitori ko ni i si ibi ti oun naa yoo le rin si ni ilẹ Yoruba, gbogbo awọn to ti bu ati awọn to ti tapa si, gbogbo awọn to ti fabuku kan, gbogbo wọn ni yoo fẹẹ gbẹsan ohun to ṣe. Bi ijọba AG ba tilẹ wọle ni West nigba naa, yoo nira gidi ti Akintọla ko ba fi ni i ṣẹwọn, koda ki ẹṣẹ to ṣẹ ma to nnkan. Akintọla mọ gbogbo eleyii, oun naa si n mura silẹ, nitori ko fẹ ki ohunkohun ba oun labo.
Nidii eyi, gbogbo bi awọn aṣaaju ati ọmọ ẹgbẹ AG ṣe n pariwo pe ki Akintọla tete da ọjọ eto idibo ni West, Akintọla ko da wọn lohun, o ni oun ko ni i jẹ ki ẹnikẹni le oun lere, oun yoo ṣeto idibo laipẹ, ṣugbọn ki kaluku ni suuru foun. Akintọla mọ idi to ṣe n ṣe bẹẹ, o fẹẹ mura silẹ daadaa ni. Awọn alatako rẹ naa mọ idi to fi n ṣe bẹẹ, awọn ko si fẹ ko roju raaye mura silẹ rara, wọn fẹẹ ko o lẹsẹ mejeeji soke lasan ni. Ṣugbọn lati ibẹrẹ ọdun 1965 yii, ko si ọrọ mi-in lẹnu awọn eeyan ilẹ Yoruba mọ ju ọjọ ti Ladoke Akintọla yoo kede eto idibo rẹ lọ. Ko kuku sẹni ti ko mọ pe ibo ọdun naa yoo yatọ si ti 1964, bi yoo ti ri ni wọn ko ti i le sọ.