Aderounmu Kazeem
Bawọn eeyan ipinlẹ Ondo ṣe jade lati dibo yan gomina ti yoo ṣakoso wọn fun ọdun merin mi-in, oriṣiiriṣi iṣẹlẹ lo ti n waye bayii.
Adugbo kan ti wọn pe ni Oke Ijẹbu niluu Akurẹ ni wọn sọ pe iro ibọn ti waye laipẹ yii, bẹẹ ni ileeṣẹ ọlọpaa loun ti ran awọn ẹṣọ agbofinro lọ sagbegbe naa.
Gẹge bi ALAROYE ṣe gbọ, wọn ni bi ojo ṣe n rọ to, niṣe lawọn eeyan to sinu ẹ, ti wọn fẹẹ ṣojuṣe wọn gẹgẹ bi oludibo gidi.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Tee-Lee Ikoro ti sọ pe loootọ niṣẹlẹ ọhun waye, awọn yoo si kapa ẹ daadaa.