Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Aago mẹta oru ku iṣẹju mẹwaa lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejila, oṣu kẹwaa yii, asiko naa ni tirela kan to fi oju ọna rẹ silẹ to n gba ọna ọlọna, fori sọ ọkọ akero Mazda to n bọ jẹẹjẹ ẹ, o si sọ eeyan mẹrin di oku ninu awọn mẹfa to wa ninu bọọsi akero naa, lagbegbe afara Ṣapade, ni marosẹ Eko s’Ibadan.
Alaye ti ọga FRSC nipinlẹ Ogun, Kọmanda Ahmed Umar, ṣe fawọn akọroyin l’Abẹokuta laaarọ ọjọ iṣẹlẹ naa ni pe tirela ti nọmba ẹ jẹ AGL 813 XX, lo wa iwakuwa pẹlu oju ọna ti ki i ṣe tiẹ to n gba bọ.
O ni eyi lo jẹ ko kọlu bọọsi akero ti nọmba tiẹ jẹ FDY 265 XA. Umar fi kun un pe eeyan mẹfa lo wa ninu mọto akero naa, ọkunrin marun-un pẹlu obinrin kan.
O ni bi tirela naa ṣe fori sọ ọkọ wọn ni ọkunrin mẹta ku lẹsẹkẹsẹ, obinrin kan ṣoṣo to wa ninu ọkọ naa si dagbere faye pẹlu.
Ijamba yii ṣee dena gẹgẹ bi Umar ṣe wi, o ni agbegbe to lewu gan-an nibi to ti ṣẹlẹ, awọn awakọ ti wọn ni oju iwoye si mọ eyi. Ṣugbọn awakọ tirela to wakọ tako ofin irinna yii lo mọ-ọn-mọ da wahala to ṣee koore ẹ silẹ, to fi di pe awọn ẹni ẹlẹni tẹri-gbasọ.
Ajọ FRSC ba ẹbi awọn to padanu eeyan wọn kẹdun, wọn si ni ki ẹni to ba n wa eeyan rẹ to rin irin ajo, ti ko si gburoo rẹ mọ lati oru naa, wa si ileeṣẹ FRSC to wa ni Ogere lati mọ si i nipa ijamba yii, ki wọn si waa gba awọn ẹru awọn ẹni to doloogbe ninu ijamba naa.
Ile igbokuu-si FOS, n’Ipara, ni wọn ko oku awọn mẹrin naa si, bẹẹ ni FRSC si tun n gba awọn awakọ nimọran pe ki wọn yee da wahala silẹ bii eyi, ki wọn yee gba ọna ti ki i ṣe tiwọn nitori oju to n kan wọn.