Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Fidio ibẹru kan to jade sori ayelujara lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, nibi ti ọmọbinrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Bukky, ti n jẹrora pẹlu ọgbẹ ada yanna-yanna lara ẹ lo mu ki ọpọ eeyan maa gbe e kiri pe o ti ku latari ada ti ọrẹkunrin ẹ, Daniel Johnson, ṣa a. Ṣugbọn ọmọbinrin naa sọrọ lori ayelujara lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, o loun ko ku, bo tilẹ jẹ pe loootọ ni ọrẹkuinrin oun ṣa oun ladaa kari ara.
O to keeyan ro pe ọmọbinrin naa yoo ku, nitori ọgbẹ ada ti ọrẹkunrin ẹ to n jẹ Daniel yii ṣa a jinlẹ pupọ, fidio naa si ṣoro lati wo fẹni ti ko ba lọkan rara. Bakan naa lo jẹ pe ẹjẹ n ṣan bala nilẹẹlẹ yara ti Daniel ti ṣa a ladaa naa ni, nigba ti fidio keji naa jade lọjọ Aje.
Ki lohun to ṣẹlẹ to bẹẹ ti Daniel Johnson, akẹkọọ ọlọdun kẹrin nileewe Tai Solarin University of Education( TASUED), fi ṣa ololufẹ rẹ to bẹẹ, ALAROYE gbọ pe eyi kọ ni igba akọkọ ti ọmọkunrin naa ti maa n lu ọrẹbinrin ẹ yii bii ko ku.
Wọn ni ajọṣepọ wọn bii ololufẹ ko wuuyan rara, nitori ilukulu ni Daniel maa n lu Bukky, ṣugbọn ọmobinrin naa ko tori ẹ fi i silẹ, wọn ṣaa n ba ere ifẹ naa lọ ni.
Ija kan ti wọn ja gbeyin la gbọ pe Daniel to n ṣiṣẹ awọn modẹẹli, arinrin oge, tori ẹ pe Bukky pe ko waa ba oun nile lọjọ Aiku, laduugbo Abapawa, n’Ijẹbu-Ode, iyẹn si lọọ ba a.
Afi bo ṣe jẹ pe ija lo kẹyin riri ti wọn fẹẹ rira wọn ọhun, to jẹ ada ni Daniel yọ si Bukky, to ṣa a lapa, lẹyin, ori, ọwọ ati ẹgbẹ kan ẹrẹkẹ ẹ yanna yanna.
Niṣe lọmọkunrin naa ro pe ọrẹbinrin rẹ to ṣa ladaa naa ti ku, lo ba fi i silẹ sinu yara naa, to sa lọ. Ori fẹnsi to wa ninu ọgba ile naa ni Bukky fo to fi bọ sodi-keji, nibi tawọn eeyan ti ri i, ti wọn si gbe e lọ sileewosan fun itọju.
Ọsibitu naa lo wa ti iroyin fi bẹrẹ si i jade pe ọmọ ti wọn ni baba rẹ n ṣe tiṣa ni TASUED naa ti ku. Eyi naa lo jẹ ko ṣe fidio lọsibitu leyin ti ara rẹ walẹ tan, to sọ fawọn eeyan pe oun ko ku o, bo tilẹ jẹ pe loootọ ni Daniel ṣa oun ladaa.
Titi ta a fi pari iroyin, yii, ko ti i sẹni to gburoo Daniel