Faith Adebọla, Eko
Gomina Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu tipinlẹ Eko ti sọ pe ijọba oun kọ lo dẹ tọọgi sawọn to n ṣewọde SARS ni Alausa, n’Ikẹja, laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee yii.
Kọmiṣanna fun eto iroyin nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Gbenga Ọmọtọṣọ lo sọrọ lorukọ Sanwo-Olu ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE lori iṣẹlẹ ọhun. O ni awọn ọta gomina lo wa nidii ẹsun ọhun, tori eeyan alaafia ni Sanwo-Olu, ko si ran ẹnikẹni niṣẹ lati lọọ dabaru awọn to n ṣe iwọde naa, o ni ẹtọ awọn oluwọde naa ni wọn n ja fun, ofin ilẹ wa si faaye gba wọn lati fi ero ati imọlara wọn han.
O ni Sanwo-Olu koro oju si ohun to waye laaarọ yii, o si fọkan awọn araalu balẹ pe ijọba yoo ri i pe aabo to peye wa fawọn to n sẹ iwọde ọhun.
Atẹjade naa fi kun un pe Sanwo-Olu yoo ba awọn eeyan ipinlẹ Eko sọrọ ni aago marun-un irọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, lori iṣẹlẹ yii ati iwọde to n lọ lọwọ naa.
Bakan naa ni alaga ẹgbẹ awọn onimọto, NURTW, l’Ekoo, Ọgbẹni Musiliu Akinsanya ti inagijẹ rẹ n jẹ MC Oluọmọ, ti sọ pe oun ko mọ ohunkohun nipa bawọn janduku ṣe de ọdọ awọn to n ṣe iwọde ọhun.
Nigba to n sọrọ niwaju geeti ile-igbimọ aṣofin, nibi tawọn oluwọde naa parojọ si, o ni ẹsẹkẹsẹ toun gbọ nipa iṣẹlẹ naa loun ti ke si awọn alakooso ẹgbẹ onimọto to ku, eyi lo si mu koun wa, lati le awọn janduku naa kuro.
Ṣugbọn ọpọ awọn oluwọde naa sọ pe irọ ni ijọba ipinlẹ Eko ati Oluọmọ n pa. Ọgbẹni Oluwaṣeyi Ayọọla to ba akọroyin wa sọrọ sọ pe bawo lawọn janduku naa ṣe ri mọto BRT ijọba lo ti ko ba jẹ ijọba lo ran wọn niṣẹ, tori inu mọto naa ni gbogbo wọn ti rọ jade pẹlu ada, kumọ, igi, okuta ati aake, ti wọn si bẹrẹ si i le awọn eeyan kijokijo.
Ayọọla ni ṣebi kamẹra to n rikọọdu ohun to ba ṣẹlẹ ninu ati layiika wa lara bọọsi BRT kọọkan, o ni kijọba ṣafihan ohun ti kamẹra bọọsi naa ka silẹ han gbogbo aye, ti ki i baa ṣe pe awọn ni wọn yọnda bọọsi ọhun fun wọn.
Ṣa, awọn ọdọ rẹpẹtẹ kan ta a gbọ pe agbegbe Ikorodu ni wọn ti wa, ti dara pọ mọ awọn to n ṣe iwọde naa bayii, lẹyin ti awọn janduku naa ti lọ.
Pẹlu orin, ilu, ijo ati akọle oriṣiiriṣii, awọn oluwọde naa ti lọọ ti ọna marosẹ Eko si Ibadan pa, bẹẹ ni wọn si gbe igi dina awọn ọna mi-in to gba agbegbe Alausa kọja, wọn ni ko sẹni to maa ni kawọn ma fi ero awọn han si aidaa tawọn ọlọpaa SARS ti ṣe.