Faith Adebọla
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide ti gba awọn awakọ atawọn araalu nimọran lati ṣe jẹjẹ loju popo nitori oriṣiriṣii nnkan tawọn janduku ti ju si oju ọna. O ni bi awọn eeyan ko ba nidii lati jade, ki wọn ma wulẹ bọ sita rara nitori oriṣiriṣii nnkan bii afọku igo, awọn oju ọna mi-in wa ti wọn ṣi gbegi di, bẹẹ ni wọn sun taya sawọn ibomin-in, eyi ti ko ni i jẹ ki awọn oju ọna jagaara.
Gomina ni awọn oṣise kolẹ-kodọti ti wa nita ti wọn ti bẹre iṣẹ lati palẹmọ gbogbo idọti ti awọn janduku atawọn ọmọọta da kaakiri ipinlẹ yii lasiko rogbodiyan to waye naa. O ni tọsan toru lawọn eeyan naa yoo fi ṣiṣẹ, ṣugbọn bi wọn ko ba ti i pari rẹ, ki awọn araalu ṣe suuru pẹlu wọn.
O fi kun un pe awọn yoo ṣe agbeyẹwo konilegbele alaago mẹjọ si mẹfa naa lati ọjọ Satide wọ ọjọ Aiku Sannde, lati le mọ igbesẹ to kan.