Kazeem Aderohunmu
Nitori rogbodiyan to ṣẹlẹ ni Lẹkki, nibi ti awọn ọlọpaa ti dana ibọn bo awọn ọdọ to n ṣewọde, ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa, Ibironkẹ Ojo ti gbogbo eeyan mọ si Ronkẹ Oṣodi, ti kabaamọ pe oun polongo ibo fun awọn oloṣelu ilẹ wa. Oṣere naa da ara rẹ lebi, pẹlu ẹkun lo si fi n tọrọ idariji lọwọ awọn eeyan.
Ninu fidio kan ti oṣere naa ṣe sita lo ti sọ pe, ‘‘Mo ma tẹ laye mi o, mo ma, tẹ mi o ma dun’bẹ o. Ẹ dẹ pa awọn eeyan, awọn ọmọ ọlọmọ ti wọn n beere nnkan ti wọn n fẹ. Ṣe wọn o le beere ohun ti wọn n fẹ ni. Mo ma kabaamọ pe mo polongo ibo fun awọn eeyan yii o.
‘‘Awọn ọmọ ọlọmọ, wọn n yinbọn fun wọn lai ki i ṣe ẹran, awọn to jẹ pe awọn lẹ maa bẹ ti ibo ba de, awọn ọmọ yii naa lẹ maa bẹ, awọn lẹ maa ni ki wọn jade. Awọn iya oniyaa, ẹ sọ wọn dẹni ti ko bimọ mọ, Ọkọ awọn eeyan, baba awọn ọmọ, ẹ sọ awọn iyawo wọn dẹni ti ko lọkọ mọ nitori atẹnujẹ. Atẹnujẹ ni mo ka gbogbo eleyii si, atẹnujẹ ni.
‘‘Bẹẹ ọjọ kan ni gbogbo wa ma ku ṣa. Ọjọ kan ni gbogbo wa patapata maa ku, iku nikan lo kari gbogbo wa, ẹ ko si ro ọjọ ti ẹ maa ku, ti ẹ maa sun ti ẹ ko ni i ji mọ.
‘‘Ṣe wọn ko ni ẹtọ lati beere ohun ti wọn fẹ ni. Ṣe a ko ni ẹtọ lati beere ohun ti a fẹ mọ ni. Mi o mọ ohun ti mo feẹ sọ mọ, mo wa lara awọn to pe awọn eeyan pe ki wọn waa dibo. Mo polongo ibo fun wọn, mo polongo ibo fun awọn oloriburuku yii o.’’
Afi suru o iyami . Olodumare akuku kowayo