Aderounmu Kazeem
Lati fopin si bi awọn eeyan orilẹ-ede yii atawọn ilẹ okeere ṣe n binu si Buhari nitori ti ko sọ ohunkohun nipa wahala to ṣẹlẹ ni too-geeti Lẹki, l’Ekoo, ọkan ninu awọn minisita ẹ ti sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori ọrọ ọhun bayii.
Ọgbẹni Sunday Dare, ẹni ti ṣe minisita fun ọrọ ọdọ ati ere idaraya, lo sọrọ yii nigba ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo lori tẹlifiṣan lana-an ọjọ Ẹti, Furaidee.
O ni gẹgẹ bi oloootọ ti Aarẹ Muhammed Buhari jẹ, ti ko si ni duro sibi ti ko si ootọ, o ti paṣẹ ki wọn wadii awọn ologun ti wọn lọọ yinbọn pa awọn ọdọ ti wọn n ṣe iwọde ni too-geeti Lẹki, l’Ekoo lọwọ aṣalẹ ọjọ Iṣẹgun to kọja lẹyin ti gomina Eko ti kede ofin konile-gbele.
O fi kun un pe nibi ipade lori aabo ilu ti Aarẹ ṣe pẹlu awọn ọmọ igbimọ ẹ lọrọ ọhun ti jẹ jade, to si ti paṣẹ wi pe ki iwadii bẹrẹ lori bi wọn ti ṣe da ẹmi awọn ọdọ kan legbodo, ti ọpọ si tun farapa yannayanna pẹlu.
O ni ni kete ti ootọ ba ti foju han, gbogbo ọmọ Naijiria naa ni Buhari yoo tun ba sọrọ lẹẹkan si i, nibi ti yoo ti sọ ohun to ṣẹlẹ gan an.