Aderounmu Kazeem
Ninu idaamu nla ni gbajumọ olorin ẹsin Islam nni, Mummen Damilọla, wa bayii pẹlu bi awọn janduku kan ṣe kọlu awọn ẹbi ẹ n’Ilọrin.
Wọn ni aṣalẹ ana ni iṣẹlẹ ọhun waye ni Gaa Saka, lẹgbẹẹ Adewọle niluu Ilọrin nipinlẹ Kwara nibi ti wọn ti pa iyawo aburo ẹ, ki wọn too tun gbe ọmọ ẹ, Abdul-Basit Damilọla, to jẹ ọmọleewe Kwara Poli lọ.
Awọn Fulani mẹrin ni wọn sọ pe wọn kọlu ẹbi ọhun, ti wọn si ko wọn sinu wahala nla bayii.
Ninu ọrọ Mumeen Damilọla, ẹni ti i ṣe Aarẹ ẹgbẹ awọn olorin Musulumi ni Naijira, o ni, “Ipinlẹ Eko ni emi n gbe gẹge bi ẹyin naa ṣe mọ, Abdul-Basit ti wọn ji gbe yii, akọbi mi ni, ileewe Kwara Poli lo ti n kawe, ko si ju ọmọ ̀ọdun mẹtalelogun lọ. Ọdọ aburo mi lo n gbe niluu Ilọrin, nitori ileewe ẹ.
“Gẹgẹ bi alaye ti ọkunrin Fulani ta a gba sile ṣe fun wa, o ni lọwọ aṣalẹ lawọn ọkunrin mẹrin kan jawọ ile, ati pe Fulani lawọn naa.
“O ni bi wọn ṣe wọle, iyawo aburo mi to wa ninu oyun ni wọn kọkọ pa, oyun ibeji lo si wa ninu ẹ pẹlu, bẹẹ ọkọ ẹ ko si nile. Yatọ si ọmọ mi ti wọn ji gbe salọ, wọn tun ko awọn ọmọ aburo mi meji, ọmọ keekeke lawọn yẹn, ṣugbọn wọn ti pada ri wọn ninu igbo. Ọmọ mi lo ṣi wa lọwọ wọn bayii, ki Ọlọrun ṣe e ni riri o.”
Ọkunrin olorin tawọn eeyan tun mọ si Ẹsin-o-gbami-laye yii ti sọ pe awọn ti fọrọ ọhun to ileeṣẹ ọlọpaa leti.