Stephen Ajagbe, ilọrin
Bi a ti ṣe kọ iroyin yii, gbogbo agbegbe ile itaja nla Shoprite to wa lọna Fate, niluu Ilọrin, ti di akọlu-kọgba, nitori bawọn eeyan ti wọn fura si pe wọn jẹ janduku ṣe ya bo ibẹ, ti wọn si n ji awọn ọja wọn ko.
Ọpọlọpọ eeyan, paapaa awọn to wa lagbegbe naa, lo n sare lọ sibẹ lati lọọ gbe ohun tọwọ wọn ba le ba, bẹẹ ni irinna ọkọ ko ja geere mọ loju ọna naa, nitori tawọn to n ko ẹru ti wọn ji ko sọda titi.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ẹṣọ alaabo wa nikalẹ, ṣugbọn o jọ pe agbara wọn ko ka awọn eeyan ọhun.
Bakan naa ẹwẹ, ko jọ pe nnkan fararọ laarin igboro ilu Ilọrin, lọwọlọwọ bayii pẹlu bawọn janduku ṣe gba igboro kan, eyi ti n da ibẹru sọkan araalu.
ALAROYE fidii rẹ mulẹ pe awọn agbegbe bii Ibrahim Taiwo Road, Sawmill ati Geri-Alimi ko rọrun, ẹni ba maa gbabẹ kọja yoo mura gidi.
Bẹẹ lọrọ ri lọna Asadam ati Irewọlede. Awọn janduku gba oju titi, wọn si n sun taya lati ma gba ọkọ kankan laaye lati kọja.