Faith Adebọla, Eko
Gomina ipinlẹ Eko nigba kan ati aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Ahmed Tinubu, ti fi ẹdun ọkan rẹ han si bi awọn janduku ṣe ba ọpọ dukia ijọba ati ti aladaani jẹ kaakiri ipinlẹ Eko, o ni iṣẹlẹ ọhun ṣe oun laaanu gidigidi, ati pe iroyin irọ lawọn eeyan n gbọn sori afẹfẹ nipa oun lasiko iṣẹlẹ naa.
Ọsan ọjọ Abamẹta, Satide, ni Tinubu sọrọ ọhun nigba to ṣabẹwo si Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ni ile ijọba to wa ni Marina, ni Erekuṣu Eko.
Tinubu to ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade toun ati gomina ṣe sọ pe ile loun wa, oun ko lọ soke okun bawọn kan ṣe n polongo kiri, ati pe gbogbo bi nnkan ṣe n ṣẹlẹ nipinlẹ naa loun n ri.
‘Emi o lọ soke okun kankan, ile ni mo wa. Ọmọ Eko gidi ni mi, emi ṣi ni Aṣiwaju ilu Eko, mi o ti i kuro ni Jagaban tawọn eeyan n pe mi.
‘Wọn sọ pe awọn kan ti ji ọmọ mi, Ṣeyi, gbe sa lọ, ṣugbọn ẹyin naa ri i lẹgbẹẹ mi bayii. Mi o san kọbọ fẹnikan ka too jọ de ibi. Iroyin ofege tawọn eeyan n gbe kiri igboro ko kan mi.’
O ni idi pataki toun fi ṣabẹwo si Sanwo-Olu ni lati wadii ẹni to paṣẹ fawọn ṣọja lati lọọ yinbọn fawọn ọdọ to n ṣe iwọde alaafia ni Lekki lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja yii, o ni ohun toun fẹẹ mọ ni toun niyẹn. O ni gomina ti sọ foun pe oun ko mọ nnkan kan nipa bawọn ṣọja naa ṣe de Lekki lalẹ ọjọ naa, oun si ti gba a nimọran lati ṣewadii lori iṣẹlẹ yii.
O ni oun ti gba gomina nimọran lati ma ṣe da luuru pọ mọ ṣapa ninu iṣẹ iwadii to fẹẹ ṣe ọhun, ki wọn ya awọn ti ọlọpaa SARS ti fiya jẹ tẹlẹ ti wọn tori ẹ gbe igbimọ oluwadii dide sọtọ, ọtọ si ni ki wọn ṣewaadi ti awọn ti ṣọja pa, atawọn to ba iṣẹlẹ biba dukia jẹ to waye lẹyin naa rin.
Tinubu fi kun ọrọ rẹ pe loootọ ni iwọde ati ifẹhonu han tawọn ọdọ naa gun le lakọọkọ ba ẹtọ wọn mu, eyi lo si mu ki ọpọ araalu ṣatilẹyin fun wọn, ṣugbọn nigba ti iwọde naa ti di ọrọ biba dukia jẹ, didana sun ile ijọba, didẹyẹ si awọn agbofinro, ọrọ naa ti kọja awọn ibeere marun-un ti wọn lawọn n beere ta ko SARS niyẹn.
Ni ipari, o parọwa pe ki kaluku lọọ fọwọ wọnu, ki ijọba le raaye yanju gbogbo lọgbọlọgbọ to wa nilẹ yii, tori inu alaafia ati igbọra-ẹni-ye ni itẹsiwaju ti le de ba ilu ati gbogbo eeyan.