Aderounmu Kazeem
Ọla Mọnde, ọjọ Aje, nileeṣẹ eto idajọ nipinlẹ Eko, ti sọ pe oun yoo bẹrẹ si ba awọn janduku ẹni afurasi ti awọn ọlọpaa mu lasiko rogbodiyan to waye l’Ekoo lọsẹ to kọja ṣẹjọ.
Oriṣiriiṣi ẹsun bii ipaniyan, idaluru, ati ṣiṣe awọn dukia ijọba ati t’araalu lofo nileeṣẹ to n ri si eto idajọ yii sọ pe oun yoo ba wọn ṣẹjọ le lori. Bakan naa ni wọn sọ pe awọn janduku ẹni-afurasi ọhun jẹ okoolelugba ati mẹsan-an (229) tọwọ tẹ, ti wọn si wa lahaamọ awọn ọlọpaa bayii.
Ninu ọrọ ti ọga agba ileeṣẹ to n mojuto ọrọ araalu lẹka eto idajọ, Ọgbẹni Kayọde Oyekanmi, sọ lo ti ṣalaye pe ileese eto idajo ti ṣetan lati ba awọn ti wọn ba jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn ṣejọ, ti awọn ti ko ba si lẹbọ lẹru yoo pada sile wọn.
Ọjọ Iṣẹgun Tusidee, ati ̀Ọjọruu, Wẹsidee, lọwọ tẹ awọn eeyan ti wọn mu yii lasiko ti rogbodiyan bẹ silẹ lẹyin tawọn ṣoja kan kọlu awọn eeyan to n ṣewọde ni too-geeti Lẹki niluu Eko.