Aṣiri ohun ti wọn ko ṣe kọlu Aafin mi ree- Oluwoo

Aderounmu Kazeem

Bi won ti ṣe kọlu awọn aafin ọba alaye, kan, ti wọn ko owo atawọn ohun iṣenbaye lọ, Oluwoo ti ilu Iwo, Oba Abdulrasheed Akanbi, ti dupẹ lọwọ awọn eeyan ilu ẹ bi won ti ṣe daabo bo aafin ẹ lasiko rogbodiyan to waye kaakiri orilẹ-ede Naijiria.

Ọba yii fi kun ọrọ ẹ pe gbogbo ẹni to ba ti n sin eeyan laye yii, wọn a pada sin oun naa, bẹẹ lo sọ pe ko dara ki eeyan ni ahun tabi ko jẹ Ọba alaye to mọ tara ẹ nikan. O ni, “Ọpọ igba ni mo maa n ṣeto iranwọ fawọn araalu, ṣe oore lo maa n bi oore, eyi gan-an lo fa a lọjọ ti wọn gbọ pe awọn janduku kan n bọ waa kọlu aafin mi, nitori ohun iranwọ ti wọn le ji ko. Funra awọn eeyan Iwo ni wọn rọgba yi aafin ka, ti wọn ni ọmọ ti wọn ba biire kan, ko waa dan iru ẹ wo.

“Ẹkọ ti mo ri kọ ninu eyi ni pe, o dara ki ọba fẹran araalu ẹ, ko si maa ṣe daadaa si wọn, emi o tiẹ tete gbọ, a kan ṣaa ri i pe wọn rọgba yi aafin kan ni, ti wọn n reti ẹni ti ẹsu a ṣe. Awọn ọmọ Iwo ko si ni i gba ki ẹnikan fọwọ yẹpẹrẹ mu ohun iṣẹnbaye ti a ko jọ saafin, niṣe ni wọn daabo bo o, bẹẹ ni wọn daabo bo ṣẹkiteriati Iwo naa pẹlu, nitori wọn mọ pe tawọn ni, wọn ko si ni i gba janduku kankan laye lati ba a jẹ”

Oluwoo ti rọ gbogbo eeyan pata ki wọn jẹ ki ogun o sinmi, ki alaafia si wa kaakiri Naijiria.

 

One thought on “Aṣiri ohun ti wọn ko ṣe kọlu Aafin mi ree- Oluwoo

  1. Iyen niwipe oba oluwo simo wipe nkan isembaye siwa. Onagbara o. Inumidun wipe ohuyin tinla. Esitinkuro ninu oko iparun tiewo tele. Oluwa yiotunbo layinloju tan patapata oaseoo orunmila atayese

Leave a Reply