Ọpọ awọn ara Eko ni wọn n fibinu han bayii lori ẹrọ ayelujara, ati ninu ọrọ ẹnu, ẹni ti won si n binu si naa ni Babajide Sanwo-Olu ti i ṣe Gomina wọn. Idi ibinu won ni pe wọn ni Sanwoolu purọ banta-banta fawọn nipa ọrọ awọn ti wọn yinbọn lu awọn ọdọ ni Lẹki lọjọ iṣẹgun to kọja, Ogunjọ oṣu kẹwaa taa wa yii.
Ohun to ṣẹlẹ ni pe nigba ti ọro yii ṣẹlẹ, ti ariwo gba gbogbo ilu lẹyin ti awọn ṣọja kan ti kọlu awọn ti won n ṣewọde ni Lẹki, gbogbo eeyan agbaye fẹẹ mọ awọn ti wọn ṣiṣẹ naa gan-an. Ṣugbọn kia ni Sanwoolu jade, to ni awọn ti wọn lagbara ju oun lọ ni wọn wa nidii ọrọ naa, awọn ni wọn ran awọn ṣọja jade, oun ko mọ kinni kan nipa rẹ.
Fun ọpọlopọ ọjọ lawọn eeyan fi n beere, ti wọn n wadii pe awọn wo ni wọn lo si Lẹki yii, koda awọn ṣọja funra wọn ni ki i ṣe awọn. Ṣugbọn o jọ pe nitori ariwo ti awọn eeyan agbaye n pa, ọrọ ti awọn orilẹ-ede aye gbogbo n sọ, lo ba ijọba yii lẹru, ti wọn fi jade lati sọ ododo. Awọn ṣọja ọwọ kọkanlelọgọrin (81 Division) jade lanaa, wọn ni loootọ ni, awọn lawọn wa si Leki, awọn lawọn si kọ lu awọn ti wọn n ṣewọde, nitori ki won ma dalu ru lawọn ṣe ṣe bẹẹ. Ṣugbọn wọn ni awọn ko deede wa o, lẹyin ti Sanwoolu ṣe ofin konilegbele lo ranṣe sawọn, iṣe ẹ lawọn si gbọ ti awọn fi wa si Lẹki.
Alaye ti Gomina Sanwoolu yoo ṣe bayii lo ku ti gbogbo aye n reti, oun nikan lo le sọ, boya ootọ lawọn ṣọja yii n sọ ni o, tabi boya irọ ni wọn n pa.