Aderounmu Kazeem
Bo tilẹ jẹ pe niṣẹ lawọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ti wọn ko ẹru ijọba ati tawọn araalu kan nigba ti rogbodiyan bẹ silẹ lọsẹ to kọja ti n sare ko tọwọ wọn da silẹ, sibẹ, gomina wọn ti sọ pe ẹni ti ko ba da tiẹ pada loni-in, ijiya buruku ni wọn fi n ṣere.
Gomina Oyetọla ni oun ko ni i fi kun ọjọ ti wọn gbọdọ da awọn dukia ijọba ati ti araalu ti wọn ji ko pada, eyi to maa dopin loni-in, Wẹsidee, Ọjọru, yii.
O ti sọ pe oni yii naa loun fun wọn mọ, ati pe ti ilẹ ọla ba fi mọ, niṣe lawọn agbofinro yoo maa ya ojule kiri, ẹnikẹni ti wọn ba si ba ẹru nile ẹ, ofin ko ni i fojuure wo o, bẹẹ ni ijiya ti yoo tẹle e yoo kọja ohun afẹnu-royin.
Niluu Oṣogbo ni gomina ti sọrọ yii nigba to n ṣabẹwo sawọn dukia tawọn eeyan kan ti sare da pada, bẹẹ lo dupẹ lọwọ wọn, to si fi awọn eeyan ti wọn ja ṣọọbu wọn lọkan balẹ wi pe wọn yoo lanfaani lati ri awọn nnkan wọn gba pada.
Nigba wo ni a ma pada senu ise nipinle Osun bayii?