Jide Alabi
Ṣeyi Makinde ṣepade pẹlu awọn onisẹ ọwọ, ọlọkada, atawon onimoto n’Ibadan
Ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni Gomina Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ ti ṣepade pẹlu awọn onisowo, onisẹ ọwọ, awọn ọlọkada atawọn ọdọ lori ọrọ awọn SARS, nibi ti onikaluku aṣoju awọn eeyan naa ti sọ ẹdun ọkan wọn.
Makinde ṣeleri pe gbogbo ohun ti awọn eeyan naa beere fun lawọn yoo ṣe lọkọọkan.
Bakan naa lo sọ nibi ipade naa pe oun ti paṣẹ pe ki wọn gba eeyan ẹgbẹrun kan sinu iṣẹ ikọ Amọtẹkun nipinlẹ naa.
Ọjọ kin-in-ni, oṣu kọkanla, lo ni awọn ikọ Amọtẹkun yii yoo bẹrẹ idanilẹkọọ, eyi ti wọn yoo pari lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu naa.
O ni awọn yoo ṣiṣẹ lori owo-ori awọn ọlọkada ati Micra ti wọn sọrọ le lori ni kete ti awọn ba ti pari iforukọsilẹ gbogbo.
Gomina waa ṣiju aanu wo awọn ọlọkada atawọn to n wa mọto keekeeke ti wọn n pe ni MICRA ti ajọ to n ri si ofin irinna mu nipinlẹ naa, ti wọn si ti ni ki wọn san owo itanran kan tabi omi-in pe ki wọn da wọn silẹ lai gba owo lọwọ wọn pẹlu ikilọ pe ki wọn maa lọ, ki wọn ma ṣe dẹṣẹ mọ.