O ṣoju mi koro (Apa Kin-in-ni)

Ki lo fa rogbodiyan yii gan-an?

Bi irọ ba lọ fun ogun ọdun, ọjọ kan bayii ni ootọ yoo ba a. Bakan naa lo si ri pe bi awọn kan ba jokoo sibi ka ti wọn n fi iya jẹ awọn mi-in, lọjọ kan naa ni awọn ti wọn n jẹ niya yii yoo yiju pada si wọn, iyẹn lọjọ ti wọn ba sun kan ogiri. Bayii lọrọ awọn ọlọpaa SARS ati awọn araalu ṣe ri. Ohun to dara ni ọlọpaa SARS nibẹrẹ, ṣe awọn adigunjale ni ijọba tori ẹ gbe wọn jade gẹgẹ bii orukọ wọn ti fi i han. Ṣugbọn nitori pe ọpọlọpọ nnkan ni ijọba orilẹ-ede yii funra wọn maa n bajẹ, ko pẹ ko jinna ti wọn fi ba ọlọpaa SARS jẹ. Ibi ti wọn ti kọkọ bẹrẹ ni ki awọn oloṣelu, awọn algbara ati awọn eeyan ti wọn mọ awọn ti wọn n ṣejọba maa lo awọn ọlọpaa yii lati fi wọn sinwo, lati fi wọn sin gbese ti ẹlomi-in ba jẹ wọn, lati lọọ fiya jẹ ẹni to ba gba wọn lobinrin, tabi to gba ale wọn lasan, ati lati maa lo wọn fi gba ilẹ onilẹ, ki wọn si maa fi wọn le awọn tẹnanti ti lanlọọdu wọn ba jẹ alagbara eeyan jade. Ṣebi nibi ti awọn SARS yii ti n ri ara wọn bii alagbara ree, ti wọn si n ri ara wọn bii ọrẹ ati ọmọ awọn ti wọn n ṣejọba, ti wọn si mọ pe ohun gbogbo ti awọn ba ṣe aṣegbe ni. Gbogbo iṣẹ ti ko bofin mu ti awọn alagbara, awọn oloṣelu ati awọn eeyan ijọba n gbe fun wọn ṣe yii, gbogbo ẹ ni owo nla n wọle fun wọn nidii ẹ, awọn ọlọpaa SARS yii si mo pe ki i ṣe pe ohun ti awọn ba ṣe aṣegbẹ ni nikan, awọn tun le di olowo rẹpẹtẹ. Eyi ni wọn n ṣe ti iṣẹ awọn ọmọ Yahaoo fi bẹrẹ, ti awọn ọlọpaa yii si pa iṣẹ ti wọn tori ẹ da wọn silẹ ti, ti wọn kuku doju kọ iṣẹ awọn ọmọ Yahoo. Nigba ti ki i si i ṣe pe awọn ọmọ Yahoo ko lẹta sori pe Yahoo lawọn, gbogbo ọmọde, ọdọ ti wọn ba ti ri ti aye ẹ daa diẹ, mimu ni, bi awọn yẹn ba si ba wọn ṣe agidi, pipa ni, tabi ki wọn di alaabọ ara. Nitori pe orọ naa ti la ọna ijẹ lọ fun wọn, gbogbo agbara ni wọn n lo, gbogbo ọna ti ko bofin mu ni wọn n lo lati fi halẹ mọ awọn ọdọ ati lati gba owo wọn. Iye eeyan ti wọn pa ko lonka, aiye awọn ọdọ ti wọn pa saye ko ṣee sọ, bẹẹ ọpọlọpọ awọn wọnyi ki i ṣe Yahoo rara. Ṣebi ohun to bi awọn ọdo yii ninu ree, ti wọn fi ni awọn ko fẹ SARS mọ, ki ijọba le wọn danu, ti ọrọ naa si di ariwo. Ṣugbọn ṣe awọn ọlọpaa SARS yii tun daa mọ ni! Ṣe wọn wulo fun ilu mọ ni! Ki lo de ti ijọba Naijiria ko ri wọn pe wọn ti kuro ni atayeṣe, wọn ti di ọbayejẹ! Bo ba jẹ ijọba tete ri wọn, ti wọn si ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe ni, ọrọ naa ko ni i ri bayii rara o. Ijọba Buhari jẹbi ọrọ yii pupọ, nitori awọn ni wọn ni aja digbolugi, o si yẹ ki alaja mọ bi yoo ti mu aja rẹ so ni. Ẹ ma jẹ kiru nnkan yii tun ṣẹlẹ mọ, ẹ tete pa ina ọtẹ bo ba ti n ru, ko too di ohun ti yoo ba ile jẹ, ti yoo ba ọna jẹ o.

 

Awọn wo ni wọn ko ṣọja apaayan  jade gan-an?

Titi di bi a ṣe n wi yii, a ko ti i ri ẹni jade pe awọn lawọn ran awọn ṣọja ti wọn yinbọn paayan ni Lẹkki. Ijọba Buhari ti purọ titi, wọn ti ṣabosi titi lori ọrọ yii, ṣugbọn fọto ati fidio ko kuku ni i purọ, kaluku lo ri i pe awọn ti wọn wọ aṣọ ṣọja lo n yinbọn. Bẹẹ ni pọn-un tilẹ ṣe ọọkan idi pupọ, kinnni naa bọ si asiko kan naa ju ki ijọba Naijiria maa wa awawi kan lọ. Awọn ṣọja ni awọn fẹẹ bẹrẹ igbaradi ologun lagbegbe ilẹ yoruba lasiko ti awọn ọdọ n ṣe iwọde, ko si ju ọjọ meloo kan lẹyin naa lawọn ṣọja de tibọn-tibọn ti wọn yinbọn pa awọn eeyan, awọn ọmọọlọmọ, ti wọn n sọ pe ohun ti awọn ọlọpaa SARS n ṣe fawọn ko dara. Ta lo waa pa wọn o! Ta lo yinbọn! Awọn ologun ni wọn kọkọ ni awọn ko ran ṣọja jade, lati igba naa ni ẹnikẹni ko si ti i jẹwọ pe awọn lawọn ṣe iṣẹ naa, ṣugbọn gbogbo agbaye mọ pe awọn ṣọja Naijiria ni, koda, bi wọn ko jẹwọ. Loootọ ni pe iwa ti wọn hu ko dara, ṣugbọn aijẹwọ yii, ati irọ buruku ti wọn n pa, ko tun orukọ tiwọn ati ti ijọba Naijiria ṣe. Bo ba jẹ awọn kọ bi wọn ti n wi, a jẹ pe a ko n iijọba ni Naijiria ree. Abi nigba ti awọn kan ba le gbogun lọọ ba awọn mi-in ninu aṣọ ṣọja, ti wọn paayan, ti ijọba wa ko si ri wọn mu, itumọ ẹ naa ni pe a ko ni ijọba kankan. Ijọba ti ko ba le daabo bo awọn araalu rẹ, iru awọn yẹn ki i ṣẹjọba. Ohun ti awọn ti wọn n ṣejọba Naijiria si n sọ ree pẹlu irọ ti wọn n pa, wọn n sọ pe awọn ko le daabo bo awọn ọmọ Naijira ni, ko si si ohun to yẹ ki wọn fi wa nile ijọba. Nitori rẹ ni ọrọ naa ko ṣe kuro ni ẹnu gbogbo ọmọ Naijiria lati ọjọ yii, koda, awọn araalu oyinbo paapaa ko sinmi, ohun ti wọn n beere naa ni pe ta lo pa awọn ọmọ ọlọmọ! Ta lo yinbọn! Awọn wo ni wọn si ran wọn lati ṣe bẹẹ! Bi ijọba Buhari yii yoo ba ni apọnle kankan nibi kan lagbaaye, afi ki wọn wa awọn ti wọn ṣiṣẹ ibi yii jade, ati awọn ti wọn ran wọn, ki wọn si fi wọn han gbogbo aye. Ohun ti yoo jẹ ki awọn eeyan, gba pe oootọ ni wọn n sọ ree, ti wọn yoo si fi oju apọnle diẹ wo ijọba wọn. Ẹ tete wa awọn ọdaran wọnyi jade, bi bẹẹ kọ, ọrọ naa yoo di wahala to le ju eleyii lọ lọjọ iwaju.

 

Jẹunjẹun lawọn minisita ta a ni, awọn kan n jẹun l’Abuja lasan ni

Nigba ti nnkan n gbona gan-an, ti wọn n sunle, ti wọn n sun mọto, ti awọn janduku si n ya wọ ile onile, njigba naa ni awọn minisita ti wọn n ba ijọba Buhari yii ṣịṣẹ pade niluu Abuja, ohun ti wọn si ni awọn n ṣepade le lori naa ni idagbasoke ilẹ Yoruba. Awọn ti wọn n ṣejọba ti wọn n pe ni minisita, aṣoju awọn araalu ni awọn naa, nitori lati ipinlẹ kọọkan ni olori ijọba ti maa n mu wọn, ohun ti wọn ṣi ṣe n mu wọn bẹẹ ni ki wọn le sọrọ lori ohun to ba n lọ ni ipinlẹ wọn, ki wọn si le dabaa iṣẹ idagbasoke ti ijọba yoo ṣe si agbegbe wọn, iyẹn ni ojulowo iṣe akọkọ ti wọn ni, ki waa ṣe awọn mi-in ti ijọba ba gbe fun wọn ni ileeṣẹ ti wọn ba fi wọn si. Ojuṣe awọn minisita yii ni lati gba olori ijọba nimọran, ki wọn si pe akiyesi rẹ si ohun ti ko ba ye e. Ṣugbọn ki la ri nibi ipade ti awọn minisita ijọba Buhari ṣe lọsẹ to kọja. Bo tilẹ jẹ pe lasiko ti wọn n ṣepade naa, gbogbo ilu lo n gbona, sibẹ, awọn eeyan yii ko mu nnkan kan sọ ninu ọrọ to n lọ laarin ilu naa, wọn ṣe bii ẹni pe wọn ko mọ pe inu rogbodiyan gidi ni ilu wa, wọn ko si ṣe bii ẹni to gbọ ohun to n ṣẹlẹ lapa ilẹ Yoruba rara. Wọn ṣepade, wọn si tuka, o si daju pe wọn ko gba Aarẹ Muhammadu Buhari nimọran lori ọrọ to n lọ. Ni orilẹ-ede to ba dara, iru awọn eeyan bayii ko jẹ ṣe minisita nibẹ, ilẹ ọjọ keji n mọ, wọn yoo le wọn kuro pata ni. Idi ni pe ọrọ araalu ko kan wọn, ko jẹ wọn logun, ẹnikẹni ti ọrọ araalu ko ba si ti kan bii tiwọn yii, wọn ki i fi wọn ṣe minisita nibi kan. Ohun to n fa eyi ko ju pe awọn eeyan yii, iyẹn awọn minisita tiwa ni Naijiria, wọn ri wa bii ẹni pe awọn ni ọga wa, awọn ni alaṣẹ, ara to ba si wu wọn lawọn le da, ohun to ba wu wọn lawọn le fi wa ṣe. Eleyii ko ri bẹẹ, awọn minisita, titi de olori ijọba, ki i ṣe ọga wa, awa la gba wọn siṣẹ, wọn n ṣiṣẹ fun wa ni. O digba ti awọn minisita ati awọn ti wọn n ṣejọba yii ba ri ara wọn bii oṣiṣẹ ilu ki nnkan too bẹrẹ si i dara nilẹ yii, nitori nigba naa ni wọn yoo le ṣe awọn ojuṣe to ba yẹ ki wọn ṣe. Awọn to wa l’Abuja wọnyi ki i ṣe minisita tiwa, jẹunjẹun ni wọn, awọn kan n fi orukọ araalu jẹun l’Abuja lasan ni. Ọlọrun yoo gba wa lọwọ wọn, ẹni to ba jẹun epo wa, to jẹun ata wa, ti ko si ṣe iṣẹ to yẹ ko ṣe fun wa, ẹsan to ba tọ si i, Ọlọrun yoo fun un. Ẹyin minisita Naijiria, ẹ ronu piwada, nitori alaidaa ni yin o.

 

Ọrọ ti Buhari paapaa sọ yẹn, korofo lasan ni

Ilu n gbina, ohun gbogbo daru, fun bii ọjọ mẹta si mẹrin, olori ijọba Naijiria ko si lanu rẹ ko sọrọ. A bẹrẹ si i bẹ ẹ, bi wọn ti n bẹ ẹ pe ko tiẹ sọrọ ni Naijiria, bẹẹ lawọn araalu oyinbo n bẹ ẹ pe ko tilẹ wi nnkan kan. Ṣugbọn igba ti yoo sọrọ naa nkọ, Aarẹ Muhammadu Buhari fi ẹtẹ silẹ, o n pa lapalapa, o fi ọrọ gidi silẹ, o n sọ eyi to ba a lara mu. Kaka ko sọrọ lori rogbodiyan to ṣẹlẹ, bi wọn ti paayan ni Lẹkki, iṣẹ to jẹ iṣẹ rere loju tiẹ, iṣẹ daadaa to loun n ṣe lo bẹre si i royin, to n ka boroboro, lai ba awọn ti eeyan wọn ku kẹdun, tabi ko tilẹ sọ pe oun gbọ pe awọn eeyan ku ni Lẹkki. Kaka bẹẹ, ija oṣelu lo n ja, to ni awọn kan lo n ro pe ojo lawọn, won n ro pe ọlẹ lawọn, awọn o le ja, to n halẹ mọgba, to n halẹ mọ awo, to n sọ pe  ẹni ba ṣe bakan, awọn yoo jẹ ẹ niya. Bawo ni olori ijọba yoo ṣe maa ṣe bẹẹ, bawo ni ẹni ti wọn fi ṣe olori orilẹ-ede yoo ṣe maa ṣe bẹẹ yẹn sọrọ lasiko ti awọn eeyan ilu rẹ wa ninu iṣoro. Ṣugbọn lara wahala ti a ko ara wa si niyẹn, lara iṣoro to n koju wa ree, nigba ti a ba ni ijọba to ro pawọn n ṣe wa loore ni. Ko si ẹnikan to lọ si ile Buhari pe ko jọwọ waa ṣẹjọba le wa lori, oun lo jade to ni oun fẹẹ ṣejọba lati tun orilẹ-ede wa ṣe, koda ẹẹmẹrin lo jade wa to wi bẹẹ, ko too di pe awọn eeyan jaja dibo fun un. Ki lo waa de ta to n ṣe bii ẹni pe awa la waa bẹ oun. Bi ijọba ko ba si wọ mọ, bi ara rẹ ko ba ya, tabi ti ilera rẹ ko ba gbe e, ko fi ipo naa silẹ fun ẹlomiiran lati ṣe e, ki i ṣe ọran ni ko wa nile ijọba. Ṣugbọn ki kinni kan ṣẹlẹ, ka ma gba pe a jẹbi yii, ko jẹ awọn alatako la oo maa bu, ti a oo maa fi ọlọpaa ati ṣọja halẹ mọ araalu, iru eleyii gbọdọ dawọ duro, ki Buhari mọ pe ijọba Naijiria loun n ṣe, ki i ṣe ti ẹya kan, ki i ṣe ti ẹgbẹ oṣelu kan, bẹẹ ni ki i ṣe ti ẹsin kan. Bi Buhari ko ba mọ eyi, yoo maa ba Naijiria jẹ si i ni o, ko si sẹni ti yoo ṣadura fu un to ba n ṣe bẹẹ, ọpọ ọmọ Naijiria ni yoo maa ṣepe fun un.

 

 

Ki lo n dun ninu awọn gomina ilẹ Hausa yii na!

Aṣọfin ilẹ Hausa kan n sọ kantankantan, Wamakko lorukọ ẹ lati Ṣokoto, o ni inu oun dun pe awọn ọdọ ọmọ ilẹ Hausa ko ba wọn kopa ninu ohun to n lọ, wọn ko ba wọn da si i, nitori awọn ti wọn n ṣe iwọde SARS naa fẹẹ fi ba Buhari ja ni. Ọrọ ti oun sọ yii, ọrọ awọn gomina ilẹ Hausa kan loun tẹle, awọn gomina kan ti wọn jade pe awọn fẹran SARS ni tawọn, nitori ko si ohun ti wọn n ṣe fawọn. Ko si ootọ ẹyọ kan bayii ninu ọrọ ti awọn yii n sọ, nitori pe iya ati oṣi to n ta wọn nilẹ Hausa ju ti ilẹ Yoruba lọ, SARS ko si ri ọmọ olowo ti yoo gba nnkan kan lọwọ rẹ ni ilẹ Hausa, nitori iwọnba awọn ọmọ olowo ti wọn ba n gbe mọto kiri nibẹ, ọmọ oloṣelu, ọmọ awọn alagbara ti wọn n ṣejọba ni, bi SARS kan ba si mu iru wọn, iṣẹ yoo bọ lọwọ rẹ. Ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibọ ni awọn ọdọ tiwa ti n fi ọwọ ati ọpọlọ pẹlu imọ iwe wọn ṣịṣẹ owo, ti wọn si n ri owo lati fi ṣe nnkan rere. Ohun to ṣe jẹ apa ọdọ wa ni SARS pọ si ju, nitori ibi ni wọn ti n ri owo gba lọwọ awọn ọdọ to n fi imọ wọn ṣiṣẹ owo, ti wọn si n gun mọto to daa kiri. Awọn gomina ilẹl Hausa yii gbọdọ mọ pe ki i ṣe gbogbo awọn ọdọ adugbo tiwa nibi ni Yahoo, awọn SARS kan ya adigunjale to n fi aṣọ ijọba ṣe iṣẹ aburu wọn ni. Ki i ṣe awọn ọmọ to n ṣe Yahoo nikan ni wọn n le kiri, gbogbo ọdọ to ba ṣe daadaa nilẹ Yoruba tabi nilẹ Ibo ni. Eyi yoo ṣajoji si wọn nilẹ Hausa nitori ko si ọmọ tiwọn ti i ṣoriire, afi awọn ti wọn ba jẹ ọmọ oloṣelu, ati awọn ọmọ awọn ti wọn n ṣejọba wọn, owo ti awọn baba tiwọn ba si ji ni wọn n na. Ki waa lo n dun mọ awọn gomina ilẹ Hausa ninu, ti wọn n sọ pe awọn fẹran SARS, nitori ko si awọn Yahoo lọdọ tawọn. Eyi to wa lọdọ tiwọn ko waa buru ju ti Yahoo lọ, tabi nibo ni ile awọn janduku ni Naijiria ti ki i ṣe ilẹ Hausa. Bẹẹ awọn gomina yii lo n ṣejọba le wọn lori, ti wọn n ji owo wọn. Ewo ni wọn waa gbẹnu soke bii ẹnu aṣiwere ti wọn n sọsọkusọ si! Ọjọ n bọ ti awọn ọdọ ilẹ Hausa yii yoo jade si wọn, ọjọ naa yoo buru fun wọn, lọjọ ti wọn yoo kigbe kiri ilu ti wọn ko ni i ri ẹni kan bayii ṣe aanu wọn.

Leave a Reply