Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Alakooso ileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ nipinlẹ Ọṣun, Arabinrin C. K. Ọlaniyan, ti kede pe ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to n bọ, lawọn akẹkọọ piramari ati ti girama yoo pada sileewe.
Bakan naa lo ni atunṣe yoo ba ilana eto ẹkọ ti wọn n ba lọ tẹlẹ nitori ijọba ti fi ọsẹ kan kun taamu ti wọn n lo lọwọ yii.
Ọlaniyan ṣalaye pe eleyii ko ṣẹyin konilegbele to waye laipẹ yii. O ni dipo ki saa eto ẹkọ yii pari lọgbọnjọ, oṣu ti a wa yii, o di ọjọ kẹfa, oṣu kọkanla, ọdun yii.