Jide Alabi
Minisita fun eto iroyin, Alhaji Lai Muhammed, ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn kan ṣe sọ ina sileeṣẹ tẹlifiṣan TVC, ati iwe iroyin The Nation.
Ọkunrin oloṣelu yii sọrọ yii lasiko to ṣabẹwo si awọn ileeṣẹ iroyin mejeeji yii lati ba wọn kẹdun ijanba to ṣẹlẹ si wọn lasiko rogbodiyan SARS, nibi tawọn janduku kan ti sọna sileeṣẹ ọhun.
O fi kun un pe ọna lati pa ẹnu awọn oniroyin mọ ni igbesẹ ọhun, ati pe ki i ṣe iṣẹlẹ to dara fun ijọba awa-ara-wa.
Agbẹnusọ fun minisita yii, Sẹgun Adeyẹmi, ni o jẹ ohun idunnu pe ko pẹ pupọ ti ileeṣẹ iroyin mejeeji fi pada sori afẹfẹ, eyi to ni yoo jẹ ijakulẹ nla fun awọn janduku to ṣiṣẹ yii, nitori wọn ko lero pe awọn ileeṣẹ iroyin naa le tete pada sori afẹfẹ.
Lai ni wọn fẹẹ fi tiwọn ko ba ẹtọ oniroyin lati maa gbohun safẹfẹ ni, bakan naa ni wọn tun fẹẹ fi ṣe ijanba fun ijọba dẹmokiresi, ṣugbọn ileeṣẹ iroyin mejeeji yii ṣiṣẹ akin, wọn jajabọ lọwọ ohun to le ko irẹwẹsi ba wọn.
Ileeṣẹ mejeeji yii, Aṣiwaju Bọla Tinubun lo ni wọn, nitori ọkunrin yii gan-an ni wọn ṣe kọlu awọn ileeṣẹ ọhun, lori ẹsun ti wọn fi kan an pe oun lo ni ki awọn ṣọja lọọ kọlu awọn ọdọ to n ṣewọde ni Too-geeti Lẹkki, l’Ekoo.