Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣiṣẹ ipinlẹ Ondo ti fẹhonu wọn han si gomina ipinlẹ naa, Rotimi Akeredolu, lori ajẹsilẹ ọpọlọpọ owo–oṣu wọn.
Awọn adari ajọ oṣiṣẹ ọhun kilọ fun gomina ninu iwe kan ti wọn fi sọwọ si i lọjọ kẹwaa, osu keje, ọdun ta a wa yii, pe awọn fun un lọjọ marun-un pere ko fi san gbogbo ajẹsilẹ owo–oṣu to jẹ wọn.
Wọn ni ki gomina ọhun maa reti iyansẹlodi awọn ni gbogbo ijọba ibilẹ mejidinlogun to wa nipinlẹ Ondo to ba fi kọ lati dahun si ibeere awọn titi di Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ ọsẹ to n bọ yii.
Eyi lawọn ohun tawọn oṣisẹ n beere lọwọ ijọba ni ibamu pẹlu lẹta ti wọn kọ si gomina. Ajẹsilẹ owo–osu kejila, ọdun 2016, fun awọn olukọ ile-ẹkọ alakọọbẹrẹ nìkan ati ajẹsilẹ owo–oṣu kin-in-ni, ọdun 2017, fun gbogbo oṣiṣẹ.
Awọn ẹtọ ti wọn tun n bẹbẹ fun ni, owo ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ fun ọdun 2018 ati 2019, owo alajẹsẹku ti wọn n ba awọn olukọ ile-iwe girama yọ fun odidi oṣu marun-un gbako, owo ajẹmọnu awọn oṣiṣẹ eleto ilera to n mojuto didena ajakalẹ arun Korona, ida aadọta ajẹsilẹ owo–osu awọn oṣiṣẹ–fẹyinti atawọn nnkan mi-in.