Aderohunmu Kazeem
Nitori bi opin ṣe ti de ba asiko to yẹ ki awọn ọmọ igbimọ to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ nipinlẹ Eko to wa nibẹ tẹlẹ lo, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti yan awọn ọmọ igbimọ tuntun ti yoo maa mojuto ijọba ibilẹ naa bayii.
Ninu atejade kan ti Olori awọn oṣiṣẹ nipinlẹ naa, Hakeem Muri-Okunọla fi sita lo ti sọ pe bi gomina ṣe fọwọ si awọn eeyan naa wa ni ibamu pelu ofin ti ipinlẹ Eko n lo, paapaa nigba to ṣe pe asiko awọn igbimọ to wa nibẹ ti tan. Beẹ lo ki wọn fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe nigba ti wọn fi wa nipo.
Atẹjade yii fi kun un pe ile igbimọ aṣofin nikan lo lẹtọọ lati fọwọ si awọn eeyan ti wọn ṣẹṣẹ yan ọhun, eyi ti wọn ni yiyan wọn da lori awọn iwe ẹri ti won ni, iwa wọn ati iriri ti wọn ti ni lori ọrọ ijọba ibilẹ.
Alaga igbimọ naa ni Họnarebu Kamil Baiyewu. Awọn yooku ni Họnọrebu Taofeek Adaranijọ, Ahmed Seriki, Biọdun Ọrẹkọya ati Akeem Bamgbọla.