Aderounmu Kazeem
Awọn olowo-aye ati onipo nla bii ọgọta ọmọ orilẹ-ede yii ni ọga ọlọpaa patapata, Muhammed Adamu, ti paṣẹ ki awọn ọlọpaa to n ṣọ wọn kuro lẹyin wọn kia bayii, ki kaluku si pada si ọfiisi rẹ.
Ṣaaju asiko yii, nigba ti wahala rogbodiyan SARS n gbona girigiri, ni ikede ọhun ti kọkọ waye pe ki awọn ọlọpaa to n ṣọ awọn olowo atawọn eeyan nla nla mi-in kiri pada si teṣan wọn, iyẹn lọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii.
ALAROYE gbọ pe nigba ti ọga ọlọpaa ri i pe wọn ko tẹle aṣẹ ọhun bo ti yẹ lo tun mu un kede orukọ awọn olowo ati ọlọrọ ti wọn n ko awọn ọlọpaa kiri gẹgẹ bii ẹṣọ bayii. Ohun to si sọ ni pe ti a ba ri ọga ọlọpaa ti awọn ọmọ ẹyin ẹ ba ṣi n ṣọ olowo kan kiri, niṣe niru wọn yoo fẹnu fẹra bii abẹbẹ.
Lara awọn eeyan pataki ti wọn ti ja ọlọpaa kuro lẹyin wọn bayii ni Fẹmi Fani-Kayọde, minisita feto ọkọ ofurufu tẹlẹ atawọn wọnyi; akọwe agba fun ijọba apapọ tẹlẹ, Babachir Lawal; Sẹnetọ Lado Yakubu, Yuguda Bashir, Uche Chukwu, Boroface Ajayi, Mutiu Nicholas, Tokunbọ Afikuyọmi, Edozie Madu, Emeka Ofor, David Adesanya, Chris Giwa, Oloye Godwin Ekpo, Pius Akinyẹlurẹ atawọn mi-in.
Ni bayii, ọga ọlọpaa Muhammed Adamu ti sọ pe gbogbo awọn ọga ọlọpaa ni ẹka kọọkan ni wọn gbọdọ kan si oun pada wi pe awọn ti ko gbogbo ọlọpaa to n sare tẹle awọn olowo-aye pada si ọfiisi wọn titi ọjọ kẹwaa, oṣu kọkanla yii.
Ṣaaju asiko yii ni igbakeji ọga ọlọpaa patapata tẹlẹ lorilẹ-ede yii, Adedayọ Adeoye, to ti fẹyinti lẹnu iṣẹ ti tako aṣa ki awọn ọlọpaa maa tẹle awọn olowo kiri. O ni, awọn to nilo ọlọpaa ko yẹ ko ju Aarẹ, igbakeji ẹ, gomina, igbakeji ẹ, olori ile igbimọ aṣofin agba ati kekere ati adajọ agba lorilẹ ede yii.
O ni bi wọn ti ṣe n ṣọ awọn olowo yẹn bii ẹni lo wọn si ibi ti ko yẹ ni, nitori araalu gan an ni wọn lẹtọọ lati maa ṣọ. Bakan naa lo fi kun un pe pupọ ninu awọn olowo yẹn ni wọn lanfaani lati gba ẹṣọ alaabo funra wọn lai lo awọn ọlọpaa ti wọn ko ti i to fun aabo ilu.