Aderounmu Kazeem
Joe Biden, ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democratic Party, ti wọle sipo Aarẹ orilẹ-ede Amerika bayii gẹgẹ bii agbejade ileeṣẹ iroyin agbaye, CNN.
CNN ti n tẹle ibo naa bọ lati ọjo to ti bẹrẹ, nigba to si ti han bayii pe Biden ti mu ipinlẹ Pennsylvania ti i ṣe ipinlẹ toun funra ẹ ti wa, CNN ni ẹni kan ki i ba yimiyimi du imi mọ, Joe Biden ti wole pata.
Ipari oṣu yii gan-an ni Biden yoo pe ẹni ọdun mejidinlọgọrin.
Ni bayii, oun ni yoo jẹ Aarẹ orilẹ-ede Amerika kẹrindinlaadọta, ninu oṣu kin-in-ni, ọdun to n bọ, ni wọn yoo si ṣe ibura fun un gẹgẹ bii Aarẹ tuntun.
Kamala Harris ni igbakeji ẹ, oun naa si ni yoo jẹ obinrin akọkọ to jẹ Asian-American ti yoo jẹ igbakeji Aarẹ orilẹ-ede Amerika.
Joe Biden ati Donald Trump ni wọn jọ fa a ko too ja mo Biden lọwọ.
Kaakiri ilẹ America lawọn ololufẹ aarẹ tuntun naa ti n yọ bayii o.